Lati ojo Aje, Monde, ojo kejilelogun, osu yii ni ayeye isin ikeyin yoo bere fun Baba Alakoso ijo Kerubu ati Serafu, Alagba Joseph Olusegun Sonde nigba ti asekagba isinku yoo waye lojo Eti, Furaide,ojo kerindinlogbon.
Gege bi a se
gbo, ile ijosin, Kerubu ati Serafu, Ebenezer Communion, to wa ni
Oke-Bunkun,Madojutimi, lona Asero niluu Abeokuta, ni gbogbo ayeye naa yoo ti
waye.
Lojo Aje,
Monde, ojo kejilelogun,legbe awon obinrere yoo seto isin ale onigbagbo nile
ijosin naa bere ni deede aago irole nigba ti apapo egbe onigbagbo iyen Organisation
of African Instituted Churches, OAIC tipinle
Ogun naa yoo seto ale isin ale onigbagbo ti won lojo Isegun, Tusidee, ni
aago merin irole bakan naa.
Lojoruu,
Wesidee, ojo kerinlelogun, legbe awon oni bibeli Naijiria, ati isokan awon
onigbagbo tijo Kerubu ati Serafu, ti eka tile Egba naa yoo se asale aisun
onigbabo tiwon naa fun ayeye ikeyin Baba
Alakoso to di oloogbe naa.
Aago mejo
aaro, Ojobo, Tosidee, ojo keedogbon, ni won yoo safihan baba naa fun igba
ikeyin fawon eeyan lati ri nile e to wa ni Iberekodo, niluu Abeokuta.
Aago merin
irole ojo naa ni asekagba aisun onigbagbo yoo waye nile ijosin naa.
Ojo Furaide,
ojo kerindinlogbon, ni isin ikeyin yoo waye laaaro, leyin naa ni eto isinku yoo
waye, ki ayeye wejewemu to bere ni papa isere Muda Lawal, to wa ni Asero.
Ojo
kesan-an, osu kefa,odun yii ni Alagba Joseph Olusegun Sonde, Baba Alakoso, ijo
Kerubu ati Serafu jade laye, leyin to lo
odun metadinlaadorun lo lo laye. Iyawo, omo, omo omo ati ijo Olorun lo fi sile
saye lo.
No comments:
Post a Comment