Oga agba fajo alaabo fijilante nipinle Ogun, Adedoyin Nureni Olanrewaju ti so pe okan soso legbe naa to wa nipinle naa ati pe oun si ni oga agba, enikeni to ba tun pe ara e ni oga fijilante nipinle naa ayederu ni.
O soro yii lakooko to n bawon
oniroyin kan soro ni ofiisi e, O so pe eni to ba je oga fun ajo alaabo naa
gbodo je eni ti olori won patapata to wa niluu Abuja iyen CG Jahun, ba yan sipo
naa.
O ni oun si ni Jahun fi se
olori won nipinle Ogun ati pe Adegbenga Adesanya ti won lo tun pe ara e ni
olori fijilante lori eto kan lori redio
ayederu ni, nitori ki i se omo egbe awon rara.
Adedoyin tun so siwaju pe “ E
je ki n soooto oro fun yin, eni to n pe ara e ni Adegbenga Adesanya, ki i se ojulowo omo egbe wa rara, nitori ko si
oruko e ninu awon to foruko sile gege bi omo egbe fijilante nipinle Ogun.
O ni awon lo akoko naa lati
fi ro awon araalu lati ma se ka oro okunrin naa kun, ki won si sora lati ma se
ba da nnkan po nipa oro to ba je mo abo.
Oga fijilante naa tun
fikun oro e pe inu awon dun pe gbogbo
awon to n gbe nipinle Ogun lo ti mo awon nipa ise takuntakun tawon ti se lori
eto abo nipa fifowosowopo pelu awon alaabo yooku bii olopaa awon agbofinro lati
saabo fawon emi ati dukia awon eeyan.
Adedoyin tun fikun oro e pe
iyalenu lo maa n je fawon pe awon kan wa ti won maa fee je nibi ti won ko se
si. O ni pelu gbogbo nnkan yoowu ti won se egbe fijilante labe alakoso oga awon
patapata CG Jahun ko nii rewesi lati ri pe won fowosowopo pelu awon eleto abo yooku.
No comments:
Post a Comment