Ojogbon Kamarudeen Balogun, to je alaga igbimo to sabewo tijoba ipinle Ogun sagbekale e ti muu dawon eeyan loju gbogbo wahala to n waye lati nnkan bii odun mefa nileewe giga olukoni
Tai Solarin College of Education
(TASCE), lawon yoo ri pe awon wa ona abayori si pelu isakoso awon ileewe naa.
Okunrin naa seleri yii lakooko to n
foro-jomi-toro- oro pelu awon oniroyin leyin ti won pari ipade pelu Gomina Dapo
Abiodun.
Nibi ipade to waye niluu
Abeokuta, ni won ti sagbeyewo awon ise ti
igbimo naa ti se lati wa ojutu si wahala to n doju ko ileewe awon olukoni naa.
O tun salaye siwaju pe’ Se ni Gomina
n foju sona lati mo ibi taa ba ise de, o fee mo awon nnkan tijoba le se, ki won
le tete se e, ki nnkan le pada si irowo-rose logba ileewe naa’
Balogun tun fikun oro e pe awon
igbimo naa ti la awon ona kan sile, eyi to le ran ileewe naa loo lowo lati le
pada si ipo ti won wa tele.
Bee lo tun so pe lara igbese tawon
tun n gbe ni lati fawon alabasise po ati igbimo naa laye lati jo sise po, o ni
eyi yoo si je kawon omoleewe tete pada si yara ikawe won.
Ninu oro ti Dokita Adeola
Kiadese, to je oga agba nileewe naa lo ti so pelu ifokanbale pe awon igbimo naa
yoo mu abajade gidi jade ni eyi ti yoo ran ijoba lowo lati fopin sawon isoro to
n dojuko won.
No comments:
Post a Comment