Asaaju rere ti ko se lafiwe ni Oloye Olusegun Osoba- APC ipinle Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 14 July 2019

Asaaju rere ti ko se lafiwe ni Oloye Olusegun Osoba- APC ipinle Ogun


 
Egbe oselu All Progressives Congress (APC), tipinle Ogun ti sapeju OloyeSegun Osoba, to je gomina tele nipinle Ogun gege bi asaaju rere ti ko se lafiwe lawon ipa to ti ko ninu oselu, won leni to fi tokaktokan sise ni.

Ninu atejade ti Ogbeni Tunde Oladunjoye, akowe olupolongo egbe naa nipinle Ogun fi sita lati fi ba okunrin naa sajoyo ojoobi ogorin odun to pe.

O so pe gege bi Osoba se n sajoyo ojoobi naa awon dupe fawon ipa to ti ko fun idagbasoke orileede yii paapaa julo nipinle Ogun. O ni gege bi asaaju, o ti lo akoko e lati fi tun opo eeyan se.

Oladunjoye tun wa sapejuwe Osoba gege bi opo nla ninu egbe, o ni nigba ti won paa ti, ko wo gbogbo e, pelu awon abuku ti won ti fi kan an, se lo ni o duro tie se e ko ye lati nnkan bi odun mejo seyin.

O ni suuru ti Baba naa ni ti ko je ki ese e ko ye lo muu se aseyori pelu idojuko ti won koju. Gbogbo e naa, o ni Osoba lo je kit un gbegba oroke ti won si yo ayo isegun.

O wa pari oro e pe loruko awon agbagba atawon omo egbe oselu APC awon ki Baba naa ko oriire ojoobi e pelu adura pe yoo se opo odun laye.
No comments:

Post a Comment

Pages