Gomina Dapo Abiodun tipinle Ogun, ti
mu da gbogbo awon eeyan Yewa loju pe ijoba oun ko ni gbagbe won ninu isejoba
oun ati pe oun ko ni fapa kan da apa kan si bakan naa loun yoo maa toju won.
Gomina soro yii lakooko to n bawon
eeyan Owode Yewa soro ni ijoba ibile Yewa South, leyin to se abewo sile iwosan ati ileewe igbalode to
wa ni Ilaro, bee lo tun loo kaakiri awon ona Ilaro si Owode lati foju ara e ri
nnkan to sele.
O so pe oun ti pase fawon ijoba
ibile lati fi oruko ona meta to je tipinle to n fee atunse kiakia bee lo tun so
pe awon ile iwosan ati ileewe alakobere lawon yoo tun sise lee lori lawon woodu
kookan lati le pese eto eko ati ilera ti ja geere fawon eeyan.
Dapo Abiodun tun fi kun oro e pe
isakoso e ti bere igbese lati gba awon akekoo jade nileewe giga to ba n wase
sise, o ni ibi ti won yoo gba lati foruko sile ninu ero ayelujara, o wa ro awon
odo lati ma se so anfaani naa nu.
O tun lo akoko naa lati dupe lowo
awon eeyan naa fun atileyin ti won se foun lakooko ibo gomina to waye pelu
ileri pe oun ko nii jawon nitan-moon.
Bee lo tun fi aidunnu e han lori bi
won se fise fale loju ona Ilaro si Owode, pelu ibeere pe ki lo de tawon
agbasese ti won gbese naa fun ko se tii pari e lati nnkan bi odun meji seyin,
ti won ko si tii se debi to lapeere.
O ni awon ti pe awon agbasese ti gbe
ona naa fun lati yoju soun ni ofiisi funipade lati mo idi to fi je ki ise naa
fa seyin. O wa muu dawon eeyan naa loju pe laipe yii ni ona naa yoo pari.
Lori ileewe igbalode to wa ni Ilaro,
o so pe ijoba oun ti n sagbeyewo lori awon ileewe naa ati pe opo won lo je pe
won yoo si si di ile ekose.
Ninu oro Olu Ilaro, ati olori Oba
nile Yewa, Oba Kehinde Olugbenle, o ro ijoba lati pese awon ohun elo igbalode
si ile iwosan ijoba to wa ni Ilaro ni ona ti yoo fi ba tode oni mu.
No comments:
Post a Comment