Lati le je ki ipinle Ogun ni ounje
ti yoo je ti mutumuwa fawon to n gbe nipinle naa atawon agbegbe to mu le ti won
to fi mo awon orileede to wa legbe won, Gomina Dapo Abiodun nijoba oun ti setan
lati pese ile oni eeka egberun lona ogoji fawon agbe lati fi dako ki isoro
airounje le dopin.
Gomina soro yii lakooko to n
forowero pelu awon agbe to wa nipinle naa, nibi eto kan to waye ni gbongan asa
ibile, Cultural Centre, Kuto, niluu Abeokuta. O ni awon agbe lawon yoo fi fun
lati dako.
O ni bijoba n gbiyanju lati dojuko ipese
asaaju rere ti yoo je ki ajosepo to
danmoran wa laarin awon olokoowo adani bee lawon yoo tun ri pe eto ogbin je eyi
to tun lagbara lati maa pese ounje fawon eeyan to wa nipinle naa atawon to mule
ti won.
O ni igbese ti n lo lowo lati rii pe
won sise po pelu ileese kan nile American lati pese eso agbado pelu afikun pe
banki orileede yii, CBN, ti setan lati satileyin fun ipinle Ogun lori idagbasoke
eto ogbin.
Abiodun tun salaye siwaju pe ipinle
yii ti foju sun awon ibi ti ile wa ti won ti le maa gbin awon nnkasnm bii
iresi, ege, agbado atawon nnkan ounje
ogbin mii in.
Pelu afikun pe gbogbo awon ona ti ko
dara to wa ni igberiko latunse yoo de ba, ki isoro le dinku fawon agbe lati le
sise won.
Ati pe ajo to n ri si abo STF yoo
tun pada lati maa pese abo fawon eeyan lori ogbin. O wa gboriyin fawon agbe
eleja fun bi won se n se ise won lona to ba igbalode mu ati pe iforowero toun
se naa yoo tun mu ojutu wa lona ti idagbasoke to dara yoo fi de ba ise ogbin.
Ninu oro ikini kaabo akowe agba
nileese to n ri si oro ogbin, Arabinrin Abosede Ogunleye, lo ti so di mi mo pe
ipinle yii idojutofo lori ise agbe ju, o wa ke si awon agbe lati fowosowopo
pelu isejoba to n loo lowo lakooko yii kawon nnkan ti won fee le te won lowo
lakooko.
Omooba Segun Dasaolu, to je alaga
fegbe awon agbe lorileede yii be ijoba lati dide iranlowo lori ile nla awon
agbe to wa ni Ogere nipa pipese abo, ina ati ona to jagara fawon lagbegbe naa.
Nibi iforowero naa lawon asoju awon agbe
oniresi, ege, agbado, eja odo atawon mii in naa ti soro lori bi ilosiwaju yoo
se de gba ogbin nipinle naa.
No comments:
Post a Comment