Alaaji AbdulRasak Ola-
Balogun, aare fegbe alajeseku apapo nipinle Ogun iyen Ogun State Co-operatives
Federation (OGSCOFED), ti gba Gomina Dapo Abiodun nimoran lati moju kuro ninu
yiyo owo awon osise, to ba fee kijoba re saseyori.
Okunrin naa soro yii
lakooko to n ba awon oniroyin kan foro-jo-mi-toro oro ni ofiisi e niluu
Abeokuta.O ni ki Gomina naa ko eko lara Seneto Ibikunle Amosun, eni to sese
kogba wole gege bi gomina lori nnkan toju e ri nipa yiyo owo ati idaamu to koju
bi asise e.
O ni Gomina tuntun naa
le saseyori ninu isakoso e nipa mimu yiyo owo alajeseku, sisan owo osise
feyinti,owo isinmi ati igbega awon osise, o ni to ba le mu awon nnkan wonyii ni
koko ko ni si wahala ninu ijoba e yii.
Ola- Balogun so pe ebe
tawon be ijoba tuntun yii pe niwongba tijoba to kogba sile ti san die lara awon
owo ti won je, awon fee ko fee kijoba tuntun yii dawo e duro, ki won san yooku
fawon omo egbe won.
O ni awon ro Dapo
Abiodun ko ma se daba lati yo owo alajeseku awon osise,awon fee ko maa san an
pelu owo osu won.
O ni awon igbimo
alakoso egbe alajeseku kookan lo ti ni ipinnu lati mu nnkan derun fawon omo
egbe sugbon tijoba ba kuna lati san owo yii sapo won, o maa n mu ijakule wa fun
erongba won.
Bee lo tun ro ijoba
ipinle Ogun lati ma se koyan egbe alajeseku OGSCOFED kere, o ni kaka bee ki won
wona bi yoo se gbooro lawon igberiko, ki won yoo si seto okoowo kekeke fun won.
Nipari oro e, O wa ro
awon oloye egbe naa lati jokoo gbiongbion pelu idaniloju oun atawon asaaju
yooku yoo mu itura bawon omo egbe naa, ko to di pe o fipo naa sile lodun 2021.
No comments:
Post a Comment