Okan lara agba oselu ninu
egbe oselu All Progressive Congress, APC, Alaaji Moshood Adegoke Salvador ti
kilo fegbe agbagba Yoruba nni Afenifere lati sora fawon nnkan ti won yoo ma so
jade, nitori ki won ma baa da wahala sile nile Yoruba.
Okunrin naa soro yii
lakooko to n bawon oniroyin soro lori bi won se lawon Afenifere se n soro to
tabuku ba Oloye Bola Ahmed Tinubu.
O fi aidunnu e han
lori bi Oloye Ayo Adebanjo ati Oloye Bode Geroge se tako erongba Tinubu lori
ati dupo fun aare lodun 2023.
Salvador tun so pe o
ti han gbangba pe awon agba Yoruba kan wa ti won n sise tako erongba awon eeyan
ile Yoruba.
O ni bawon agbagba naa
se n se je nnkan to ba ni lokanje nitori pe o ni e o le ri awon agba eya yooku
lati sise tako ara won.
O salaye pe kaka ki
won maa soro nipa ipo aare odun 2023, ti enikeni ko ti le so bo se maa ri, ohun
to ni o ye ko je won logun lati wa ojutu si isoro to n dojuko awon omo Yoruba.
Ariyanjiyan to ni
Alagba Ayo Adebanjo se pe ko seni to ti je aare ni South east ko soooto ninu e,
o so pe o wa ninu itan pe Oloye Nnamdi Azikiwe, to koko je aare lorileede yii,
apa ibe lo ti wa.
Salvador tun so pe ko
tii si asaaju Yoruba to ti ro awon eeyan lagbara nile Yoruba leyin Tinubu, o ni
gomina tele nipinle Eko yii igbadun isejoba wole Yoruba.
O wa beere lowo gbogbo
awon to n tabuku Tinubu , ki won wa so ipa ti won le ko lori ipenija eto abo to
n dojuko won lorileede yii.
No comments:
Post a Comment