Eso alaabo So- Safe Corps nipinle Ogun ti so pe awon ti wa ni igbaradi lati pese abo fawon araalu fun ti ayeye itunu awe todun yii, ti yoo waye lojo kerin si ojo karun un, ati leyin odun, ki gbogbo nnkan le loo bo ti to ati bo ti ye.
Ninu atejade
kan ti Ogbeni Moruf Yusuf, to je agbenuso fun ajo naa fi sita lo ti salaye pe
gbogbo eto lo ti wa ni sepe kaakiri ipinle Ogun fun abo odun naa.
O salaye pe
lati ojo Aiku, Sannde, ojo keji titi di ojo Abameta, Satide,ojo kejo osu yii
lawon osise alaabo naa yoo ti wa lati pese abo fawon to ba fee rin irinajo lati
ibi kan loo si ekeji, nitori awon mo pe
opo awon eeyan ni won yoo fee rin irinajo.
Okunrin naa
tun so pe lati aaro di asale lawon osise alaabo won yoo fi maa wa lenu ise, ti
won yoo si so bi nnkan ba se n lo.
Nigba to n
so erongba won ti won fi ya ose kan naa sile fun akanse ise, Ogbeni Moruf so pe
lati dabobo emi ati dukia awon eeyan, lati rii pe ko saye fawon to ba fee da
wahala sile nigboro.
Bee lo ni
awon tun wa fun lati din iwa toogi tabi daluru ku lakooko odun naa. Lati rii pe
awon eeyan bowo fun ofin lagbegbe won ati lati sise po pelu awon osise alaabo
mii in.
O wa fi
akoko naa ro gbogbo awon to je oga ajo naa lawon ijoba ibile ati ijoba ibile
idagbasoke lati mojuto awon osise won lawon
akoko naa ki won ko ma se faye gba igbakugba fun won.
Gbogbo awon
to wa ni eka okan-o-jokan ninu ajo So-Safe Corps ni won so pe won ti wa nimura
sile tawon ohun gbogbo ti won yoo lo si ti wa nile ki odun naa le dun yungba
kaakiri ipinle Ogun.
O wa ro awon araalu lati fowosoo pelu ajo alaabo
naa, kawon naa si yera fawon nnkan to le da wahala sile nitori So- Safe Corps
ko foju sile kawon kan maa da alaafia araalu ru.
No comments:
Post a Comment