Yinka ati Ramoni ti dero atimole o, epo petiroolu ni won loo ji wa. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 6 June 2019

Yinka ati Ramoni ti dero atimole o, epo petiroolu ni won loo ji wa.


Yinka Olufowobi, eni odun metalelogbon ati Tunde Ramoni, eni odun marundinlaadota, ni won ti wa latimole awon olopaa nibi ti won je faaji lori esun jiji epo petiroolu wa.

Gege bi atejade ti Abimbola Oyeyemi, agbenuso fawon olopaa nipinle Ogun gbe jade lo ti so pe awon olopaa olopaa ti won wa ni Ridiimu,ti won n so Simawa ni won mu awon mejeeji naa.

A gbo pe se ni won rawon mejeeji naa ninu moto toyota alawo buluu ti nomba e je RC 862 AAA  pelu ike ti petiroolu kun inu e.

Won ni bi won se ri awon olopaa ni won fee sa lo tawon olopaa olopaa si gba tele won, ti won si ri won mu.

Ninu iwadii tawon olopaa se lawon afurasi naa ti jewo pe abule Oloparun lona Ogijo lawon ti lo maa n ji epo wa pelu ifowosowopo awon to n gbe ni lagbegbe Ilara ni Ogijo lawon fi n sise naa.

Ni bayii, Komisanna awon olopaa nipinle Ogun, Bashir Makama ti ni ki won bere iwadii lori awon ti won mu naa, ki won si foju bale ejo loju ese.No comments:

Post a Comment

Pages