Asiko taa wa yii ki i
sakoko to dara fegbe awon to n fi moto sowo, Road Transport Employees Association of
Nigeria (RTEAN), iyen roodu tipinle Ogun, nitori bi won se fesun
orisiirisii kan alaga egbe naa, Ahmed Kuku, ti won lo n lepa emi awon oloye egbe e, bee lo tun je awon omoose won to wa
niofiisi won lowo osu.
Gege bi a se gbo, lati
odun to koja ni awuyewuye naa ti n loo ninu egbe naa, nitori bi won se ni alaga
naa se n se, ko te awon omo egbe lorun mo, idi niyii tawon yen fi so ninu osu
kejila odun naa ninu ipade egbe naa pe awon ko nigbagbo ninu ijoba e mo.
Latigba naa la ti gbo
pe egbe roodu ko se ipade olosoosu ti won maa n se mo, bee ni won ni alaga won
ohun, tun sa kaakiri.
Eyi ti won wa so pe o
buru ju ninu oro naa gege bi esun ti won fi kan Kuku ni pe se lo n lo awon
olopaa kan lati maa fi hale mo awon omo egbe ti won tu asiri pe alaga won sowo
egbe naa basubasu.
Iwadii fi ye wa pe
lati nnkan bii odun meta seyin ti okunrin naa fi wa nipo alaga egbe naa ko ni
banki ti won fowo egbe pamo si, ti ko si le si si akosile bi won se nawo naa.
Ninu oro Tiwalade
Akingbade, to je akowe fegbe roodu nipinle Ogun lo tun ti tan imole soro naa pe
emi gbogbo awon ko de lowo alaga won ti won n pe ni Kuku naa, idi niyii tawon
fi tete pariwo sita.
O so pe ninu osu kin
in ni odun yii legbe naa ti ko leta si alaga egbe naa lati fipo e sile, ki won
le se iwadii lori awon esun sisowo basubasu ti won fi kan an naa.
Sugbon to so pe o ko,
kaka bee awon olopaa lo fi n hale mo awon alatako e yii.
Lara awon ti akowe
egbe naa so pe Kuku halemo kaakiri ni Kayode Inaolaji, igbakeji egbe naa,
Munirudeen Jimoh, igbakeji akapo, Folami Folarin, igbakeji alaga nipinle Ogun,
Yahya Oriyomi.
Awon yooku ni Akeem Kolawole, Kayode Kehinde, ati Akibu
Titilayo (Efele), atawon oloye egbe yooku.
Bee lo so pe awon ti
ko leta fifi ehonu won han si ileese awon otelemuye iyen DSS,ileese awon olopaa
lati bawon gbe igbese lori wahala to sele naa.
Bakan naa lawon osise
won to wa ni ofiisi won ni Abeokuta naa tun so ti won pe wahala to n sele ninu
egbe naa ti ran awon, nitori alaga won ko fawon lowo osu.
Sugbon alaga ti won
fesun kan naa, Kuku ti so pe ko si ooto kankan ninu esun ti won fi kan oun.
No comments:
Post a Comment