Awon agbanipa kolu Segun Akanni, Oludasile iwe iroyin The Drum Online - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 6 June 2019

Awon agbanipa kolu Segun Akanni, Oludasile iwe iroyin The Drum OnlineIbeere tawon to n gbo nipa isele to sele si oludasile iwe iroyin Drum Online, Ogbeni Segun Akanni  ni pe ta lo fee demi okunrin naa legbodo ti won n lepa emi e.

Gege bi a se gbo, ori lo ko okunrin naa yo nigba tawon ti won fura si gege agbanipa kolu okunrin naa, ti won si luu ni alubami, ti won  ko si so pe awon ko paa.

Iwadii fi ye wa pe se lawon eeyan naa kolu okunrin to nileese Prince  Genesis Concepts nileepo Mobil Filling Station to wa ni Gbagada, niluu Eko.

Awon bii mewaa ni won so pe won digbolu oun nikan ni asale ojo naa, kekere ni ko ni oro naa, bi ko ba se pe awon eeyan wa nitosi, won ko so pe awon ko paa.

Oniroyin wa gbo pe awon eleyinju aanu ni won gbe Segun loo sile iwosan nibi to ti n gba itoju.  Ohun to n ko awon eeyan lominu ni pe kin ni okunrin oniroyin naa se ti won fi fee pa.

Bo tile je pe Segun Akanni naa ti pariwo sita pe kawon eeyangba oun, nitori emi oun ko de mo, awon kan fee gba emi oun lojiji.


No comments:

Post a Comment

Pages