Fun bi odidi wakati marun un lawon odo bii
ogorun un ni won tu jade loni in lati fi ehonu won han ni Iresa-Adu, nijoba
ibile Surulere, nipinle Oyo lori bi won se ni enikan to pe ara e ni Abraham
Olafimihan Adeyeye Oyerinde se kede ara e gege bi oba tuntun fun Aresa-Adu tiluu
Iresa-Adu.
Gege bi oniroyin wa se
gbo,pelu ibinu ni awon odo naa fi jade sita lati so pe awon lodi si bi okunrin
naa se pe ara e loba nitori awon mo pe aye naa si sofo titi digba ti ile ejo
giga to wa ni Oyo yoo fi se idajo.
Gbogbo ona to wonu
igboro ilu lawon odo naa di, ti won si tun dana si taya lawon oju titi ti won
si n korin ote lorisirisi ti won fi n paroko si eni to pe ara e ni Oba naa lati
jade sita nibikibi to ba farapamo si.
Oro naa ki i se kekere
o, se lawon onilu atawon olorin okunrin naa faragba ninu iya naa, se ni won lu
won, topo awon tori ko yo si ki ilu boa be agbada won, nitori kowo iya ma baa
te won.
Sugbon gbogbo nnkan
loo sile nigba tawo eso alaabo ilu to fi mo awon otelemuye atawon olopaa atawon
mii in jade lati wa pese abo fawon araalu.
Iwadii fi ye w ape ile
ejo giga kan ti Oyo to wa ni Orile - Igbon lagbegbe ijoba ibile ni won tip e ejo
ti nomba e je HOI/04/2019, lojo ketadinlogun, osu kerin, odun yii nibi ti
won ti ro ijoba ipinle Oyo ati Okunrin
ti won lo n pe ara e ni oba naa, iyen Omooba Adeyeye Oyerinde lati daa duro titi ti idajo
ejo ti won pe yoo fi waye.
Awon ti won tun pe
lejo naa ni Gomina ipinle Oyo, Adajo
agba ati komisanna feto idajo, akowe ijoba ibile , Raji Oloyede, Tunde Oloyede,
Nathaniel Oyediran ati Oyewumi Oyeniran.
Pelu bi won se ni ejo
naa ti n loo lowo, se ni won ni Adeyeye Oloyede yi ase ileejo da nigba to n
tesiwaju lati je ki won foun joba niluu Aresa-Adu.
A gbo pe iwode gba
awon olopaa atawon alaabo yooku lopo wakati ko to di won rii yanju, Won ni awon
gan an ni won dogbon pe oba naa kuro loo pamo fun abo ara e.
Nigba to n soro nipa
isele naa, agbenuso fawon olopaa, Ogbeni Gbenga Fadeyi so pe gbogbo nnkan ti n loo le bayii, o ni ise
awon ni lati je ki alaafia wa ni gbogbo iluu Iresa-Adu. Awon ko si nii tiju lati
se.
No comments:
Post a Comment