Adura ni maa fi bori awon ota mi- Ibikunle Amosun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 6 June 2019

Adura ni maa fi bori awon ota mi- Ibikunle AmosunGomina tele nipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun, ti so pe oun ko beru enikeni to ba fee koju oun ati pe adura loun yoo fi mu won. Nitori ko si nnkan ti won fee fi oun se.
O soro yii lakooko tawon olori esin musulumi nile Egba, ti Imaamu agba nile Egba, Alaaji Liadi Orunsolu saaju loo sadura odun fun un nile molebi e to wa ni Akin Olugbade, niluu Abeokuta.
O so fawon musulumi to wa nibe lojo naa pe ki won maa fadura ran oun lowo, o nib o tile je pe enikan so foun pe kin ni oun se fun won, pe won po sugbon oun so pe meloo ni won, ti won ba je ogun, ki won gbadura pe koun mu igba ninu won awon ota oun.
Amosun tun so pe“ Sugbon adura te e o maa gba ni oruko Allah, nitori Allah ni yoo bori won, ni temi, mo ti se iwon ti mo le se, mi o ki i se Olorun, eeyan alara bi tiyin lemi naa n se, mo le ni ebi temi o amo Olorun mo, nitori e ni mo se n so pe alaafia ni iseda mi wa fun.
O tun so pe nigba toun de lojo isegun, Tusidee, oun ri awon nnkan to n sele,awon osise agbasese si n se ise won lo nitori a ti sanwo won, a ko je won lowo,nipa ipinle Ogun ni gbogbo e, inu oun si dun.
Gomina tele naa tun so pe “Biriji Adatan si Saje si Mokola, a ti sanwo e fawon agbasese taa gbe ise fun, won yoo se e. Lati Ilugun siMokola,won yoo sise e. Idi niyii ti mo fi so pe emi ko ni gomina akoko nipinle yii, opo won lo je pe ti won ba ti kuro lori oye nise won maa n ku..
O ni inu oun dun pe Olorun ko je ki toun ri bee, nitori awon eeyan si n sise, nitori a ti sanwo won, bee lo ni won yoo maa ba ise loo titi towo tawon fun yoo fi tan. O wa fi kun oro e pe bo tile je pe oun ni musulumi akoko to yoo je gomina, oun tun dupe pe oun ko doju ti won.No comments:

Post a Comment

Pages