Arabinrin Onimo-ero Noimot
Oyedele- Salako, to je igbakeji gomina nipinle Ogun ti so pe inu ijoba to wa
lode yii ko dun sipo ti eto eko wa nipinle naa, nitori opo ipenija tawon
omoleewe n koju lawon ileewe ijoba.
Obinrin naa soro yii
lakooko to n sabewo sawon ileewe kan lati fi mo ibi ti won ba eto eko de lawon
ileewe alakobere ati girama tijoba. Pelu ileri pe gbogbo idojuko naa lawon
yoo bere si nii yanju loju ese.
Lara awon ileewe to
sabewo si naa ni ileewe alakobere Reverend Kuti, to wa ni Nawarudeen, Ileewe
alakobere ati nosiri Nawarudeen, Isabo , Ileewe ekose ijoba iyen Government Technical and Vocational ,
Oke - Ijeun , ati ileewe girama St.Peters ati Alakobere Community ni
Olomore.
Igbakeji gomina to
bere abewo gege bi ase lati odo Gomina Dapo Abiodun, ni akowe agba nileese eto
eko, Ola- Olu Aikulola atawon osise mii in nileese naa tele lo ni eru ba
nigba ti won ri okan ninu yara eko, nibi tawon omoleewe ti deyin ko ara won
kekoo ni yara ikekoo kan naa.
Niomot so pelu itara pe beeyan ba fee ko eko,
ko si saseyori, atunse gbodo lawon eka eto eko nipinle naa, O ni opolopo awon
nnkan to je ohun amulo lo ye ki won pese lati dojuko ipenija yii, nitori ki i se
ipinle naa lo ye ki ina eto eko e maa jo ajoreyin.
O wa mu da awon eeyan
ipinle Ogun loju ijoba Gomina Dapo Abiodun ko nii fakoko sofo lati satunse
gbogbo awon nnkan ti won ba n fee lawon ileewe kaakiri ipinle Ogun. Gbogbo awon
isoro won yii lo ni yoo di afi seyin nidii eto eko.
Bee lo gba awon obi nimoran lati mo iwulo eto
eko, o ni ko si ilekun ti ko le si lawujo, o ni ki won je kawon omo won wa
nileewe kaka ki won maa gbe oja le won lori.
No comments:
Post a Comment