Eni- owo Michael Adebayo , to je olori fawon bisobu ti ijo Anglican ni ekun Yewa, ti gba ijoba to wa lode yii nipinle Ogun nimoran lati ma se fi apa kan da apa kan si ninu awon imayederun idagbasoke ti won yoo ba maa se.
O
gba won lamoran yii lakooko to n bawon eeyan soro fun ti ayeye odun kewaa
sinoodi tijo naa maa n se lodoodun eyi to waye ni soosi St. James, Oke- Odan,
nipinle Ogun.
O
ni ki won rii pe awon ise idagbasoke naa kaakiri gbogbo ekun meteeta to wa
nipinle naa, nitori gbogbo won lo parapo di ipinle kan, ko si ye ki won fi awon
nnkan wonyii du awon eeyan naa.
Eni-
Owo Oluwarohunbi tun fikun oro e pe opo awon eeyan ipinle naa ni won ko je
anfaani mudunmudun ijoba nitori ti won ko se awon ohun imayederun sodo won
paapaa julo lawon igberiko.
O
ni bawon eeyan ko se ri anfaani ijoba je
nnkan to mu kawon eeyan so ireti ni, nitori ileri aimuse tawon to wa nijoba maa
n se ti won ki i muse je ki nnkan su won, ti ko si je ki won nigbagbo ninu won
mo.
O
wa mu idaniloju wa pe pelu adura gbogbo igba ati amoran, o da oun loju pe
Olorun yoo wonu awon asiwaju naa, won yoo si le se nnkan tawon araalu n fe lona
ti yoo fi kari gbogbo agbegbe meteeta nipinle Ogun.
Ninu
oro Gomina Dapo Abiodun, eyi ti igbakeji e, Noimot Salako-Oyedele, je loruko e
loti dupe lowo gbogbo awon eeyan Olorun paapaa ijo Anglican fun atileyin ti won
se ni gbogbo igba ti ipolongo fi n loo lowo pelu gbogbo nnkan ti won foju won
ri sugbon ti won duro ti oun ti won si je ki alaafia waye kaakiri ipinle Ogun.
O
ni bi alaafia ba fee joba laarin awon elesin, gbogbo won gbodo fowo sowopo lati
le je ki ojo iwaju ipinle Ogun goke. O mu da awon eeyan to wa nibi ayeye naa
loju pe ijoba to wa lode yii yoo satileyin orisi awon eto elesin to le mu
igbega, isokan ati alaafia ba gbogbo eeyan.
Gomina
wa ki ijo naa fun aseyori ti won se lori ayeye ti won se naa ti akole e je "Woo,
a tii ri ", O wa gbadura pe ki Olorun tubo je ki alaafia maa joba nipinle
Ogun.
Bakan
naa ewe, lori erongba lati wa atunse si eto-eko to ti denukole nipinle
Ogun,igbakeji gomina tun sabewo sawon ileewe kan nijoba ibile Yewa
Ninu
abewo to se, eyi toun ati Onarebu Biodun Akinlade jo se ni won se de ileewe
Baptist Day, to wa ni Oke-Odan, nibe lo ti so pe oun to gbe oun sabewo debe ni
lati wo ipenija tawon ileewe koju nipa eto- eko nipinle naa.
O
wa seleri fun won nibe pe ijoba to wa lode yii yoo ko ileewe igbalode o kere
ju, eyo kookan sawon woodu to wa nijoba ibile nipinle yii.
No comments:
Post a Comment