Bi iroyin to n loo nigboro yii ba fi le je
ooto, o ye kawon egbe osere tiata Yoruba kun fun adura gidi ki won si bere si
nii wa ona atunse laarin ara won.
Gege bi a se gbo, won lawon agba
osere onitiata ti won ti ku, ti won degbe osere naa sile n binu gidigidi, won
ni inu won ko dun sipo ti tiata wa lori bi won se fonka yannayanna.
Okan lara
awon oga onitiata to ni ka fi oruko boun lasiri lo soro yii lakooko to n ba
oniroyin wa soro, o ni opo igba lawon agba osere to ti ku naa maa n fara han
oun.
Gege bo se
wi, o ni ki i se egbe osere tawon eeyan kan fara jiya fun ko to di pe won wa ni
isokan ti won fi n je Association of Nigeria Theatre Practioner, ANTP, lo wa
fonka, ti won si ti pa egbe naa patapata.
O salaye pe ifaseyin
ti won mu ba egbe naa lo je tawon egbe ti won tun loo da sile naa ko se wa
nisokan, to je pe awon to wa nibe naa mo amo won ko fee pariwo sita.
Ati pe eto
to ye ko maa to si won ni won ti taa danu fawon mii in, nitori bi won se fonka
naa, ti won ko si tun je ki irepo ko wa laarin won.
Agba osere
tun salaye siwaju pe bo ba wu won, ki won ka oro oun danu sugbon ti won ba fee
kawon osere naa tun wa nipo iyi ati eye tawon araalu ka won si, ki won se nnkan
ti yoo mu kawon agba osere to ti ku ti won degbe naa sile fi le yo si won, ki
won si pa ote run laarin ara won, bi bee ko, ojoojumo ni iyapa yoo maa waye
tawon ti ko mo nipa ise naa yoo maa kere won.
No comments:
Post a Comment