Egbe oselu All Progressives Congress
(APC), eka tipinle Ogun ti sapejuwe bi igbimo to n gbejo nipa ibo gomina to
waye, se da ejo ti egbe oselu Labour pe nu bi omi isanwo gege bi igbese to dara
ju.
Lojo Eti, Furaide, ana, ni igbimo
naa da ejo naa nu nitori won ni ejo ti won pe naa ko lese nile ati bo se je pe
gbogbo awon eleri ti won pe ati agbejoro won ko se yoju sibi igbejo to n lo
lowo naa. Koda won tun ni ki egbe oselu Labour naa tun san egberun lona
eedegbeta naira, owo itanran feni ti won pe lejo.
Ninu atejade ti Ogbeni Tunde Oladunjoye, to je
akowe olupolongo egbe naa fi sita leyin ti igbejo naa waye lo ti so pe igbese
to dara, ati bi egbe oselu naa ko se tele ejo to ti won pe naa, o ni o je eyi
to yanilenu pupo.
O tun so siwaju pe “Nnkan taa ti n reti tele
ni, nitori awon to pejo naa gan-an kuna lati fi fawon eeyan sawon ipo kan ti
won n dije fun un, ti won si n reti lati se ibaje leyin ti idibo waye. A ti mo
egbe oselu Labour tele nipinle Ogun pe iwa won ni lati dabaru eto idibo, nitori
ona atije ti won”.
Oladunjoye tun fikun oro e ninu atejade naa pe ohun to
dara fun ijoba tiwa-n-tiwa lati faye sile fawon sile fawon to n fi akoko awon
igbimo to n gbejo sofo lori ibo ti
gbogbo awon eeyan jade di nirowo-rese laisi wahala kankan.
“O wa gboriyin fawon igbimo naa lori
ipinnu ti won gbe naa, eyi to ni o wa labe ofin ile wa todun 2010.
No comments:
Post a Comment