Gomina ipinle Ogun, Dapo Abiodun ti gba awon
agunbaniro ti won sinru ilu owo keji, iyen Batch B, nimoran lati rii se won fi
ti omoluabi se ohun gbogbo ti won ba n se lakoko ti won fi sin ile baba won, ki
won si tun ko ara won nijanu lati year fun iwa ibaje.
O soro yii lakoko ti igbakeji e,
Onimo-ero Noimot Salako –Oyedele jise to ran sawon agunbaniro naa nibi ayeye
igbaniwole ati ibura ti won se fawon eeyan naa, eyi to waye ninu ogba won,
niluu Sagamu.
Gomina so pe ni ki won maa wo ti eya
tabi esin ti onikaluku won ti wa amo ki won jumo wa nirepo lati lo ore-ofe ti
won ni lati fi mu idagbasoke wa si orileede won.
O tun ro awon to sese fee bere si nii sinru
ilu naa lati mo nnkan ti won n se, ki won si rii pe won kopa ninu awon ayeye to
le mu ipenija wa fun won lojo iwaju.
Gomina naa gba won niyanju lati rii
pe won samulo awon ofin ati ilana ti won ba la kale fun won lakooko ti won wa
ni ipago ti won wa naa, ki won si fowosowopo pelu awon alase won ti won yoo maa
satona fun ose meta.
O ni idunnu oun ni pe wiwole awon
agunbaniro naa se konge ibere isejoba
tuntun nipinle Ogun, lakooko tawon sise loorekoore lati je ki idagbasoke ba eto
oro aje ipinle naa.
“Gomina wa pari oro e pe ijoba oun
ti gba lati mu ireti awon eeyan ipinle naa se nipa igbagbo ti won ni ninu won
lati bere awon ise akanse ti yoo mu itumo bawon araalu pelu idaniloju pe yoo
tun wulo fawon iran to n bo.
Ko to to akoko yii ni adele alaga
fun igbimo ajo agunbaniro iyen NYSC nipinle Ogun, Kolawole Fagbohun, ti ro awon
agunbaniro naa lati sin orileede won tokantokan, ki won si tun rii lona ti yoo
wulo fun won lojo iwaju, pelu ikilo lati pawon ofin inu ogba naa mo.
Awon agunbaniro egberun meji ati
irinwo ni won sayeye igbaniwole fun won ti adajo agba nipinle Ogun,Onidajo
Mosunmola Dipeolu, eni ti Adajo Nasiru Agbelu soju fun bura fun won.
No comments:
Post a Comment