Ki i se oro enu lasan, bi won ba daruko okan lara omo Yoruba atata, eleyinju aanu, to ti tun igbe aye opo awon eeyan se, Otunba Rotimi Paseda, je okan ninu won, asaaju si tun ni pelu.
Lojo Abameta,
Satide, ni okunrin omo bibi Omu- Ijebu, nipinle Ogun sajoyo ojoobi, to fi n dupe lowo Olorun pe o da oun si, opo awon
eeyan ni won baa sayeye naa ti won si n ki i ku oriire.
Agba oselu
ni okunrin naa, eemeji otooto lo fi jade dupo gomina labe egbe oselu UPN ati SDP, bi okunrin naa ko tile wole sibe iyen ko
nii dawo iranwo e duro, titi di akoko yii lo si n fi nnkan ti Olorun fun un
lati fi ran awon alaini lowo.
Bawon
agbagba lokunrin lobinrin se n je anfaani bee lawon omode naa je nibe nipa
gbigbe ikekoo lakooko isinmi awon omoleewe kale nibi tawon omoleewe alakobere
titi de girama ti je anfaani lawon agbegbe to wa nipinle Ogun.
Iyen nikan
ko, omo olojoobi tun sagbekale ajo kan ti won pe ni Otunba Rotimi Paseda Foundation,
nibi topo awon eeyan tun ti je anfaani ironilagbara.
Ohun to mu
ki okunrin to tun je onisowo ti Olorun Oba fopolo jinki se yato si tawon eeyan
ni pe ko fi tegbe oselu kankan se nipa aanu e fawon eeyan, o fee je pe awon ti
ki i somo egbe e lo n je anfaani naa se.
Ninu iwa
asaaju rere to tun fi le le ni pe ko ya egbe oselu kan sapa kan, opo ipa lo ti
ba awon oloselu bii Otunba Gbenga Daniel, Omooba Gboyega Nasir, Seneto Buruji
Kashamu atawon mii in, ko si si nnkan mii in bi ko se lati wa ona ti idagbasoke
yoo de ba ipinle Ogun, tawon araalu yoo
kuro ninu ijoba amunisin.
Bee ni ko se
ya opo eeyan lenu nigba ti okunrin naa loo ki Gomina Dapo Abiodun ku oriire
lakooko to wole ibo gomina to koja, to si seleri lati sise po pelu okunrin naa.
E ma je ko ya yin lenu pe bi okunrin yii se nileese nla lorileede yii bee naa lo ni ni oke-okun, toun atawon oyinbo jo n jokoo se ipade po. Bee ni ko tun fawon eeyan Olorun sere, nitori oun gan-an agba emi ni.
Meloo lo ka
ninu eyin adepele fawon ohun ribiribi to ti se, igbagbo ati erongba awon araalu
ni pe ka ni won fun okunrin naa loore- ofe lati tuko ipinle ati orileede yii ni
yoo se ju bo se n fee lo lati mu iderun wa.
Idi niyii to
fi ye ka ki okunrin oloripipe, ojise Olorun, eleyinju aanu, ti ko ni oruko meji
taa le pe ju omo YORUBA ATATA, ku oriire, e o se opo odun laye.
Olorun yo tubo fun Otunba rotimi paseda ni emi gigun ati alafia ara.
ReplyDelete