Idowu Adenekan agba osere tiata fee sayeye ifilole fiimu Eewo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 23 June 2019

Idowu Adenekan agba osere tiata fee sayeye ifilole fiimu Eewo



Gbogbo eto lo ti n loo lowo bayii fun ti ayeye ifilole fiimu tuntun ti gbajumo osere tiata nni Idowu Adenekan fee gbe jade. Eyi to pe akole e ni EEWO.

 Gege bi a se gbo, lojo Aiku, Sannde, ojo kokanlelogun,  osu keje, odun yii  iyen osu to n bo naa ayeye ifilole ati isafihan fiimu naa yoo waye.

Gbongan Olusegun Obasanjo Presidential Library, to wa lona NNPC, Lemme, niluu Abeokuta ni ayeye naa yoo ti waye bere ni deede aago mejila osan.

Gbegude tiluu Ososa, Oba Adetoye Alatise ni Baba ojo naa, nigba ti Alaaji Raheem  Sulaiman, to nileese epo ati gaasi SLAAB ni olugbajejo pataki.

Elere ojo naa ni Saheed Osupa,oba orin nigba ti Otunba Bolaji Amusan,topo mo si Mista Latin, Afeez Owo ati Musiliu Bebe yoo dari ojo naa.

Okunrin naa wa so pe aye wa fawon to ba fee ra ankara egbejoda ti won fee lo lojo naa lati pe Lola Aromasodun 08038427496, Wumi Ajiboye 08039163014, Taiwo Adenekan 080 25907106. Sola Popoola 07032200101 ati Senegal 08069420320
     

No comments:

Post a Comment

Pages