Ese kan aye, ese kan orun ni osise alaabo
So-Safe Corps kan, eni odun mejidinladoota, Kehinde Aigbe, wa ni osibitu FMC,
to wa ni idi Aba, niluu Abeokuta, nibi to ti n gba itoju lowo, lori bawon adigunjale
se yinbon mo on lakooko ti won doju ija ko ara won.
Gege bi atejade ti agbenuso eso
alaabo naa, Ogbeni Moruf Kolawole Yusuf fi sita, lo ti salaye pe ni nnkan bi
aago meta oru, ojo Aje, Monde, oni, lawon adigunjale lo digun ba awon eso eyan
agbegbe Olorunsogo, Oke- Lantoro legbee soosi End- Time Ministries.
A gbo pe nibi ti won ti n dawon eeyan
naa laamu ni won ti tawon alaabo So- Safe Corps lolobo, tawon naa si gbera lati
gba awon eeyan naa sile.
Sugbon oto ni nnkan tawon eso alaabo
lero, oto ni nnkan ti won ba, nitori bi eni pe awon adigunjale naa ti mura won
sile, nitori bi won se ri won ni won dana ibon bo won, tibon si ba Kehinde
nikun.
Lojiji ni won si ti sare gbe loo si
osibitu nibi to ti n gba itoju, Agbenuso awon eso alaabo naa ti wa seleri pe
gbogbo akitiyan lawon ti n sa lati rii pe owo tea won adigunjale naa.
No comments:
Post a Comment