Bola Solate, Arewa obinrin to je okan
lara oludasile iwe iroyin oloyinbo ni ileese iwe iroyin City People, fami eye
daa lola gege bi oludasile iwe iroyin to pegede julo.
Nibi ayeye naa nibi ti won ti fami
eye da awon to ti laami laaka nipa ise aje, akoko e to waye nipinle Ogun, eyi
ti won se ni gbangan Providence, to wa ni Lemme, niluu Abeokuta ni won ti fi
awoodu saponle obinrin naa.
Opo awon to wa nibi ayeye naa ni won
gboriyin fun ileese iwe iroyin City People lori bi won se fun Arewa Obinrin naa
ni awoodu naa, won lo ka ju ami eye ti won fun, nitori akinkanju obinrin ti ki i
fi imele sise ni.
Olu Itori, Oba AbdulFatai Akorede
Akamo ati Oba Sowemimo, to je Olu Owode naa fi ade ori won sure fun oloriire
ojo naa, ti won sapejuwe gege bi odo oludasile iwe iroyin.
Ninu oro ti Bola Solate, lo ti lo
akoko naa lati dupe lowo iwe iroyin City People, eyi ti Seye Kehinde je oga won
fun bi won yan oun ti won si foun lami eye naa.
O ni lati nnkan bi odun
mewaa toun ti da ileese iwe iroyin sile, oun ko nii lokan pe won le se iru eye
bee foun, pelu nnkan to sele yii, o tun fi foun lafaani lati tubo tesiwaju ninu
ise iroyin toun se ninu iwe iroyin PublicFaces.
Foto ayeye naa tun reee
No comments:
Post a Comment