Won ti kede iku Alagba Adesina
Ajibode, topo awon eeyan mo si Aji. Gege bi Ogbeni Ibukun-Olu Ajibode, tawon
eeyan mo si Blesodec, to je aburo oloogbe naa se wi, lojo Aje, Monde, ana, ni
iku pa iku oju okunrin naa de nile e to wa ni Remo.
Okunrin naa la gbo pe o je gbajumo
awon to tun ero omi se iyen Plumber, ilu mo on ka si ni pelu ise e yii, nitori
ko seni ti ko fi bee mo ni gbogbo ilu Remo.
Blesodec tun sapejuwe Egbon e yii,
gege bi onisuuru eeyan, to ko awon eeyan mora, o ni ko si nnkan ti okunrin naa
ko le fi saanu fun eeyan.
Idi niyii to fi so pe opo awon eeyan
to gbo nipa iku e lo n ka lara, to si n dabi ala loju won, se won lawon mii in
ko gbagbo a fi gba ti won to ri oku okunrin naa.
Latigba naa titi di akoko yii la gbo
pe awon eeyan fi n ro lo sile okunrin naa fun ibanikedun. Lara awon ti won so
pe won ti de be ni Oloye Bolajoko Lawal, Ogbeni Tajudeen Somefun alaga fegbe
awon to n se ero omi atawon mii in.
Ni bayii, won ti gbe oku Alagba
Adesina Ajibode, ti wa ni ile igboku si ni OSUTH, to wa ni Sagamu, nigba ti won
yoo maa dajo ti won yoo sinku laipe.
Alagba Adesina fi iya, iyawo, omo,
ati omo omo sile saye lo.
No comments:
Post a Comment