Bo tile je pe latigba ti ijoba ipinle Ogun ti fofin de egbe awako iyen NURTW ati egbe awon to n fi moto sowo taa mo si Roodu iyen RTEAN ni orisirisi awuye ti n loo laarin igboro lori bi won se gbe igbese naa.
Sugbon ni bayii,
Tiwalade Akingbade, to je akowe egbe roodu nipinle Ogun, ti fatileyin e han si
igbese naa gege bi eyi to dara to si le mu eso rere jade wa.
Okunrin yii soro naa
lakooko to n ba oniroyin wa soro, o so pe inu oun dun si igbese naa nitori yoo
mu ayipada ati ilosiwaju ba egbe awon onimoto mejeeji lojo iwaju.
O fikun oro e pe oun
nigbagbo ninu awon igbimo tijoba Dapo Abiodun sagbekale e pe won yoo sise naa
bo ti to ati bo ti ye.
O tun fikun oro e pe
igbese naa lo je ki opin de baa won wahala to ti n waye laarin awon oloye egbe
latigba ti ipolongo ibo ti bere.
Tiwalade wa ro
gbogbo awon omo egbe onimoto ti won ni ikunsinu lati gbagbe gbogbo nnkan to ti
sele naa ki won si fowosowopo pelu awon igbimo naa, ki Alafia le joba laarin
egbe awako ati onimoto to fi mo awon olokada naa.
Akowe onimoto naa tun so pe ‘ Igbese tijoba
gbe naa te mi lorun, to si tun je atewogba fun idagbasoke ipinle Ogun, bi eyin
naa ba ri, e o sakiyesi pe kijoba tuntun to de ni wahala ti be sile, lori ta ni
yoo se olori fegbe awon onimoto, mo ro pe igbese tijoba gbe lati fofin de wa
dara pupo.’
O tun fi kun oro e pe ijoba gan-an ti mo pe
pelu bi nnkan se n loo nigba naa laarin awon egbe onimoto, ko si abo to peye,
won si le da wahala to le mu itajesile waye laarin,nitori e lo ni won se gbe
igbese naa.
Bee lo tun so pe
ipinle Ogun ti wa ni alaafia lati nnkan bi odun mewaa seyin, ti ko si akosile Kankan
ija waye laarin egbe awako ati onimoto.
O ni oun ro pe nnkan tijoba fee se ni lati je
ki alaafia tubo joba ni won se sare gbe igbese naa ati pe gbogbo egbe lo niwee
ofin to n dari won.
O wa pari oro e nipa
riro awon ti won ni ikunsinu lati gba ofin laaye ko sise e, ki i se nipa dida
wahala sile ni won fi le yanju nnkan. O ni alaafia gbodo joba nipinle Ogun..
No comments:
Post a Comment