Lale ojo Isegun, Tusidee, ni nnkan naa ti sele, bo si se tii sele, ko see pariwo, nitori won ki i pariwo nnkan bee nile Yoruba sugbon nigba ti yoo fi di aaro, ojo keji, Ojooru, Wesidee, iroyin ti tan jake jado, pe akoni oba ti waja. Oba Haruna Olaoye Abass ti loo sibi agba re.
Ko seni to
gbo nipa iku Oba naa ti ko se ni kayefi, ki i se pe baba naa ko dagba, odun
merinlelaadorun un lo lo laye sugbon awon araalu e tun fee ki Oba naa tun pe ju
bee lo nitori iwa rere e.
Nitori e ni
ko se ya opo awon eeyan lenu nitori bi won se rawon omo ilu atawon alabagbe se
ya loo si aafin Oba naa lati mo boya ooto loba naa waja tabi iro ni.
Bawon to ti
je minisita to je omo ilu naa se yoju bee lawon seneto, komisanna naa ko
gbeyin, lati wa seye ikeyin foba ilu won.
Lati nnkan
bi aago meje aaro lawon eeyan ti n ro de aafin lojo naa, nigba to di aago
mejila osan ni won gbe oku Kabiyesi naa loo si mosalasi jimo nibi ti won ti
sadura si oku e, ko to di pe won gboku e pada wa si aafin nibi ti sin in si.
Gege bi a se
gbo, lojo kokandinlogbon, osu kewaa, odun 1925 ni won ni Oba Haruna ni idile ebi Egburu ni Iga,
Oke-Agbo, Ijebu-Igbo.
Sugbon
lodun 1992, ti aye ipo Olori-Ilu ati Lapoekun si sile to si kan idile Iga ni won ranse pe Oba naa lati wa dije,
to si bo sipo oye naa lojo kefa, osu kefa, odun 1992.
Idunnu
subu layo won lojo kokandinlogbon, osu keji, odun 1997, nigba ti won fun un ni igbega si oba, ori oye
naa lo wa titi to fi waja. Awon abule to wa labe e le ni ogorin.
Won ni
lakooko to fi wa lori oye lo mu ilosiwaju ati idagbasoke bawon eeyan e ni Oke-
Agbo. Lara awon to wa nibi isinku oba naa ni Seneto Gbenga Kaka, Ogbeni
Babatunde Ipaye, Onarebu Dupe Adelaja, Ogbeni Bayo Adesanya atawon mii in.
Ninu ise
ibanikedun ti Otunba
Gbenga Daniel, gomina tele nipinle Ogun ran lo ti sapejuwe Oba naa gege bi
asaaju rere, to si tun fi awokose gidi lele.
Atejade
naa ti Ogbeni Ayo Giwa fi ranse, lo ti ni Gbenga Daniel ki awon ebi oba naa ku afera ku, o ni
latigba ti oba naa ti wa lori oye lati odun 1992, lo ti sa ipa e lati ko oore
wolu naa.
O
ni titi aye loruko Oba naa ko ni pare ninu iwe itan fawon aseyori e, o wa tun
ki gbogbo awon Oke-Agbo ku afera ku, o ni loooto lawon padanu oba rere, ti won
yoo si maa ranti e titi lae.
Ninu oro ti Seneto Gbenga Kaka, lo ti so pe ebun nla ni Oba naa
je nigba to wa laye, o ni ki i se fawon Oke- Agbo nikan, fun gbogbo ile Ijebu
lapapo.
No comments:
Post a Comment