Gbajumo akewi nni, to filuu Sotubo, Sagamu sebugbe, Bayo Oyebamji topo awon eeyan mo si Captain tun ti fee gbe ewi tuntun mii in jade, Ironu omo Oduduwa lo pe akole e.
Gege bi
okunrin tawon kan tun mo si Ariwajoye se wi, o ni kaseti ati fidio ewi naa lo
so pe o yato sawon eyi toun ti n gbe jade, nitori ise opolo inu e ko see royin.
Oga akewi to
ti figba kan gbe awon kaseti bii Dende oro, Tifun- tedo ati Apero salaye pe
ohun ti kaseti naa duro lori ni bi isokan yoo se deba iran ile Yoruba.
O tun so pe
Omo Yoruba loun fi sori ewi naa lati le ronu ibi ti won ti n baa bo ati ibi ti
won baa de. Bee lo tun menuba awon isoro to n dojuko iran yoruba lakooko yii,
tawon to ye ko gbe igbese ko gbe, ti won n wo ran.
Olabamji tun
so pe kaseti ironu omo Oduduwa naa ki i se nnkan ti won le foju lasan wo, to ba
jade, eyi to ye ki gbogbo omo Yoruba gbo, ki won tun maa tun gbo ni, ki won si
fi pamo fawon iran to n bo.
Laipe yii lo
so pe ewi naa yoo jade si fidio agbelewo.
No comments:
Post a Comment