Boroboro ni Odomokunrin kan, omo
ogun odun, Esun Monday, n ka nigba towo awon alaabo So- Safe te gbe o ji adie,
to si ti n pe to ti n jawon lole bee.
Gege bi Ogbeni Moruf Kolawole Yusuf,
to je agbenuso fun eso alaabo So-Safe se wi, lojo kejidinlogbon, osu kefa, lowo
te Odomokunrin naa ni agbegbe Tejuola, Owode nibi to ti ji adie mejo ko lawon
ko.
O so pe awon gbo pe awon agbegbe
Tejuola ati Mola Audu to wa ni Owode Yewa ni Monday ti ji awon adie naa ko, ko
to di pe owo te e.
Won ni awon eso alaabo So-Safe Corps
to wa ni agbegbe onidagbasoke Ifekowajo LCDA lo tele Omokunrin naa lakooko towo
te e de gbogbo ibi to ti ji awon adie naa ko.
Nigba to n jewo, o so pe ki i se
igba akoko ree toun ti maa n ji won ladie, oun ti wa lenu e tipe, ati pe boun
ba ti ji, oun ni onibaraa toun maa n ta fun lojo oja Owode.
Bo tile je pe Monday so pe oun ko
ranti oruko obinrin naa sugbon momi loun
maa n pe e, loju ese ni won so pe won ti wa obinrin naa lo sugbon won ko ba a.
Bee lo tun jewo pe eedegbeta naira
loun maa n ta okookan adie toun ba ji gbe fun obinrin naa. Ni bayii, won ti fa
Monday le awon olopaa Owode Yewa lowo, nigba tawon yen naa tit e siwaju ninu
iwadii won.
No comments:
Post a Comment