Pelu bi nnkan se n loo
yii, afaimo ki won maa folopaa mu Omooba Adeyeye Oyerinde lori bi won lo se
tapa si ofin ileejo nitori o pe ara e ni oba, eyi to mu ki wahala fi be sile
niluu Aresa- adu, nipinle Oyo. Lojooru, Wesidee, to koja.
Gege bi a se gbo,
gbogbo ona ni Agbejoro ti ebi Emiolu to ye ko fi omo oye sile, iyen Agbejoro
Abiodun Julius declared fee fi ba Oyerinde faa lori igbese to gbe naa to mu ki
opo dukia baje lakooko ehonu tawon odo ilu naa se lojo naa.
Ohun taa gbo ni pe
Agbejoro naa ko mu oro naa ni kekere rara, won iwa adase ti Oyerinde se to fi n
pe ara e ni oba tuntun fun Aresa-adu tiluuIresa-adu laigba ase lowo awon ebi
tipo naa wa lowo won ni won ni okunrin naa yoo salaye ara e.
Ninu oro Agbejoro Julius
lo ti so pe ki lo de ti okunrin naa fi fee je ki oro olobade tiluu Aresa-adu da
wahala nla sile nipa bo se kuna lati so ara e di oba lojiji ni Aresa to n lo
awon egbon e gege bi afobaje, o lo je eyi to lodi sofin sileejo.
O salaye siwaju pe
igbese ti Oyerinde gbe lodi si ase ileejo ti won pe ti nomba e je HCI/04/2019, eyi to so pe o da gbogbo awon
toro kan lowo ko fun ipo oba ti won fee je losu to n bo.
O ni ko si nile Yoruba
yii nibi teeyan kan fi le fi ara e joba. O so pelu idunnu okan e lori bi gbogbo
araalu to fi mo ebi Oshunbiyi nibi ti Adeyeye Oyerinde ti wa se fi iwa ainitiju
ti omo won se han, ti ko dun mo won ninu,
Agbejoro naa wa so pe
oun ti gba ase lati odo awon onibara oun iyen ebi Aresa - Emiolu lati pejo lori bi Oyerinde se lodi sofin
ileejo.
Bee lo ni awon afobaje
niluu naa ti pase fun agbejoro won lati tele ipejo lori iwa imotaraeni ti
Oyerinde wu yii.
No comments:
Post a Comment