Ko le sija laarin awa asofin ati gomina ipinle Ogun- Oluomo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 10 June 2019

Ko le sija laarin awa asofin ati gomina ipinle Ogun- OluomoOlori ile igbimo asofin tuntun ti won sese yan, Olakunle Oluomo, to wa lati agbegbe Ifo kin in ni, ti muu dawon eeyan ipinle Ogun loju pe ko le sija kankan laarin awon ati Gomina Dapo Abiodun, amo sa, awon yoo maa tele nnkan ti ofin ba so.

O soro yii lakooko to n bawon oniroyin soro leyin ti won fi je olori ile igbimo asofin kesan an nipinle Ogun. O ni awon yoo rii pe ajosepo to danmoran wa laarin awon ti gomina atawon asofin.

O fikun oro e pe ile igbimo asofin ki i se lati maa ba ijoba tabi gomina ja bi ko se lati maa se nnkan tofin ba so laarin awon  igun mejeeji.

Oluomo tun fi idunnu e han bawon omo ile igbimo asofin se faa kale lati di olori won laini alatako kankan, o ni eyi tumo si pe gbogbo awon lawon setan lati sin awon eeyan won ti won wa soju fun.

O ni gbogbo ona awon yoo rii pe awon eeyan ipinle Ogun je mundunmudun ijoba awarawa to wa lode yii.

Nibi ayeye ifilole awon omo ile igbimo asofin tuntun nipinle Ogun to waye naa ni Onarebu Olakunle Sobukola ti dabaa  lati yan Olakunle Oluomo gege bi olori ile igbimo asofin laini alatako nigba Onarebu Adegoke Adeyanju sikeji aba naa.

Leyin eyi ni won yan Onarebu Dare Kadiri to wa lati Ijebu North keji gege bi igbakeji olori ile igbimo asofin. Awon oloye ti won tun yan an laarin ara won ni  Onarebu Yusuf Serif to wa lati Ado Odo kin in ni ni won fi se olori omo egbe to poju, nigba ti Onarebu Bashir Oladunjoye lati Sagamu kin in ni je igbakeji olori omo egbe to poju lo.

Awon yooku ni Atinuke Bello to wa lati Odogbolu ti won fi se olopaa egbe nigba ti Sola Adams  to wa lati Ijebu East je igbakeji e.  Ganiyu Oyedeji to soju won lati Ifo keji ni olori omo egbe to kere nigba ti Jemil Akingbade lati Imeko Afon je igbakeji e. Muse Lamidi  to wa soju Ado Odo Ota keji ni won fi se igbakeji olopaa omo egbe to kere. 

Leyin ti won setan ni awon oloye tuntun naa loo ki Gomina Dapo Abiodun ni ofiisi e.


No comments:

Post a Comment

Pages