Ijoba Dapo Abiodun ko ni rewesi lati mu ijoba tiwa-n-tiwa rorun faraalu- Noimot Salako- Oyedele - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 12 June 2019

Ijoba Dapo Abiodun ko ni rewesi lati mu ijoba tiwa-n-tiwa rorun faraalu- Noimot Salako- Oyedele



 Bo tile je pe ojo manigbagbe lojo kejila osu kefa je lati nnkan bi odun merindinlogbon ninu itan orileede yii ti won si maa n ya soto lawon ipinle kan sugbon todun yii yato nitori pe won ti fi pe ori ijoba tiwa- n- tiwa, eyi ti won se kaakiri orileede yii, ti won si n je kawon eeyan mo pe ojo naa ko le pare lailai.


Ni papa isere MKO Abiola, to wa ni Kuto, niluu Abeokuta, lawon omo ipinle tu yaya jade wa lati wa si ayajo ijoba tiwa-n-tiwa naa, nibi ti orisirisi eto ti waye.

Ninu oro Onimo-ero Noimot Salako- Oyedele , igbakeji gomina ipinle Ogun so loruko Gomina Dapo Abiodun lo ti ro awon oloselu lati ma se rewesi tabi fa seyin lori nnkan ti June 12 duro le lori nipa ijoba tiwa-n-tiwa tawon eeyan janfaani e loni in.

O tun gba awon omo Naijiria nimora lati lo ifaraji ti MKO Abiola ni lori oro ijoba tiwa-n-tiwa pese isejoba tuntun fun anfaani awon omo orileede yii ko le te siwaju, ko si mu eso rere jade.

Igbakeji gomina tun lo akoko naa lati dupe lowo awon omo ipinle Ogun fun igbagbo ti won ni ninu ijoba tuntun yii pelu idaniloju pe ijoba Dapo Abiodun  ti setan lati pese isejoba tuntun lati mu igbe aye rorun fawon araalu.
.

O ni awon ti pinnu lati pese isejoba tuntun lati mu inu awon eeyan dun iru eyi to ni Oloogbe Oloye MKO Abiola ni lokan lati se laifi ti eleyameya si pelu ileri pe erongba awon ni lati mu ki ipinle Ogun goke agba ju bo se wa loo.


Ninu oro ti Olakunle Oluomo, to je olori ile igbimo asofin nipinle Ogun, lo ti sakiyesi pe  ijangbara ojo kejila osu kefa ko gbodo lo lasan, o wa gba gbogbo awon oloselu lati wa ni isokan lati fi le gbogun ti osi ati iponju lorileede yii.

Lara awon to tun soro nibi ayeye to waye naa ni okan lara omo MKO Abiola, awon mii in to tun soro ni Sylvester Odion.
 Wale Oshun, Femi Aborisade, Arabinrin Funke Fadugba atawon mii in.

Ko to to akoko yii ni igbakeji gomina ti saaju awon eeyan ipinle naa lo sile molebi MKO Abiola, to wa ni Oja -Agbo, Gbagura, niluu Abeokuta, nibi ti akanse adura ti waye. 

Nibe lo ti seleri pe ijoba awon yoo te siwaju lati maa sise rere ti MKO Abiola se gege bi awokose rere lati tan ihinrere awon igbadun to wa ninu ijoba tiwa-n- tiwa kaakiri ipinle naa.


No comments:

Post a Comment

Pages