Lati le dekun agbara
ojo to le mu emi lo tabi ba dukia je, ijoba ipinle Ogun ti kilo fawon to n gbe
lawon ibi ti odo wa, ki won ye dale soju agbara, lati le dekun omiyale, agbara
ya soobu.
Ikilo yii waye lakooko
ti igbakeji gomina nipinle Ogun, Noimot Salako- Oyedele, sabewo sawon ibi ti
ojo to ro lojobo, Tosidee, ose to koja se lose.
O ni okan lara awon
isoro to koju awon eeyan ni aimoye odun seyin lawon ile ti won ti gbo, ti won
ko latunse latile wa, iru awon ile atijo bee wa lara awon ohun to sokunfa
omiyale naa.
O ni akiyesi tawon tun
se ni bi ko se si aye fun omi lati san daadaa lo n je ki won ya oju ona ti moto
n rin ati pe bawon eeyan se n dale sawon odo yen ko je ki omi raye loo bo se ye
ko lo, idi niyii to fi kilo fun won pe ki won ye dale sinu odo mo.
Igbakeji gomina tun so
pe asise bi won ko se faye sile lati je ki odo san ki won to ko awon ile kan
tun wa lara awon ohun to tun sokunfa.
O ni lati le fopin
sawon isoro yii, idi niyii tijoba ipinle Ogun pelu ifowosowopo ijoba apapo se n
gbe igbese lati bere ise lori awon nnkan to le fa ijanmba omiyale, ki won si
fopin sii.
Nigba to n soro nipa
odo Sokori, eyi to so pe o gba gbogbo Abeokuta koja, Enjinia Kayode Ademolake,
to je akowe agba nileese to n ri si oro ise ati imayederun nipinle Ogun, so pe
odo naa wa lati odo Ogun oun lo si de
Itoku niwon kilomita oodunrun to gba opo biriji koja.
O fi kun oro e pe opo
awon biriji ti won se ni omi ko raye lati gba ori e daadaa lati koja, idi niyii
to fi n ya kaakiri, to fi de awon oju ona ti moto n gba.
Nigba to n soro lori
bijoba se fee da si lati dena omiyale yii, akowe agba nileese to ri si awujo,
so pe awon ti setan lati bere si ni bawon eeyan soro lori ki won ye dale sinu
odo mo ati ona ti won le je ki agbegbe won wa ni imototo.
Lara awon to ba
igbakeji gomina sabewo kaakiri naa ni Lanre Bisiriyu, to je olori awon osise,
Alaaji Salisu Shuaibu.
Awon yooku ni akowe
agba nileese to n ri si oro ise ati imayederun, Kayode Ademolake, Yetunde Dina
ati Nafiu Adebiyi pelu awon mii in.
No comments:
Post a Comment