Owo awon eso alaabo So-Safe Corps to
wa ni Idi-Iroko, nipinle Ogun ti te Arakunrin kan, eni ogbon odun, Abimbola
Kareem, lori esun adigunjale, to lo fole onile.
Gege bi atejade kan ti Ogbeni Moruf
Yusuf, agbenuso fun eso alaabo naa fi sita, lo ti salaye pe lojo Abameta,
Satide, ana an, lowo te okunrin ti won lo n gbe ni ojule Igboku Adebayo, nijoba
ibile Ipokia, nipinle Ogun.
A gbo pe ile eeyan meta otooto ni
Abimbola fo niluu Ajegunle labe ijoba ibile Ipokia.Ile to je ti Ogbeni Jerry ni
adugbo Mede, Ile ti Nawe, ni Ago Egun, ati ti lya Peter ti gbogbo e wa niluu Ajegunle.
Awon nnkan ti won ri gba lowo e
lakooko towo te e ni
Egberun marun un le ni eedegbeta,
ero laapu toopu, foonu, bata tuntun meji,sokoto tuntun meji atawon nnkan mii in
to ji ko.
Gbogbo tawon eleso abo naa gba lowo
e ni won ti ko fawon olopaa tesan Idi-Iroko lowo lakooko ti won fa afurasi naa
le won lowo.
Awon olopaa si ti tesiwaju ninu
iwadii won.
No comments:
Post a Comment