Olori ile igbimo asofin ipinle Ogun ni asaaju rere, ti ko se fowo ro seyin ni Osoba - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 16 June 2019

Olori ile igbimo asofin ipinle Ogun ni asaaju rere, ti ko se fowo ro seyin ni Osoba


 
Olori ile igbimo asofin tuntun ti won sese yan, Olakunle Oluomo ti sapejuwe gomina tele nipinle Ogun, Oloye Olusegun Osoba gege bi asaaju gidi ati Baba rere fawon ipa to ko lakooko ti ibo gbogbogboo waye ati nigba ti won fee yan olori ile igbimo asofin. O ni iru e sowon lagbo oselu.

Okunrin naa soro yii lakooko toun atawon oloye egbe nile igbimo asofin tipinle Ogun sabewo sodo Osoba nile e to wa ni Eko, lojo Abameta, Satide, to koja yii lati le fie mi imoore won  han si Baba naa

Oluomo fi idunnu e han pelu idaniloju pe gbogbo awon eeyan ipinle naa ni ki won maa reti nnkan gidi lati odo ijoba, pelu afikun oro e pe ile igbimo asofin layipada rere yoo de ba nipa idagbasoke ohun rere. 

O tun seleri pe ile igbimo asofin akoko yii yoo tesiwaju lati le je kawon ise akanse lawon agbegbe tun loo soke si. O tun wa muu da Oloye Osoba loju awon omo ile igbimo asofin eleekesan yii yoo sise pelu ijoba atawon araalu fun ilosiwaju.

Ninu oro Oloye Osoba, o sakiyesi pe idagbasoke ipinle Ogun lo gbodo je ohun pataki fawon omo ile igbimo asofin, nitori ijoba  tiwa-n-tiwa gbodo dele doko. O wa gbawon niyanju lati rii pea won asaaju ile igbimo asofin gbodo wa nisokan, ki won si sise po pelu ijoba kawon nnkan tawon eeyan n fee le te won lowo.

Lara awon to tele Olori ile igbimo asofin, Olakunle Oluomo lo ni igbakeji e, Onarebu Oludare Kadiri, ati olori awon omo ile igbimo asofin to poju Onarebu Abiodun Yusuf .


No comments:

Post a Comment

Pages