Ese o gbero ni gbongan Providence, Lemme, niluu Abeokuta, lojo Aiku, Sannde, nigba tileese iwe iroyin oloyinbo nni, City People fun Ogbeni Tunde Adeyemo, oludasile ileese awon to n ta ile ti won pe Pelican-Valley ni ami eye nla lati fi mo riri ileese e.
Bo tile je
pe ki i se okunrin to je oniroyin nileese MITV, to je omo bibi ilu Ibadan nikan
ko lo gba awoodu lojo naa sugbon o je
okan lara ile to ti lami laka lati ran awon ilu lowo ki won le di onile.
Olu Itori,
Oba Fatai Akorede Akamo ati Olu ti Owode, Oba Kolawole Sowemimo ni won gbe awoodu naa
fun un leyin ti won ti so die nipa itan igbesi aye Tunde Adeyemo.
Nigba toun
naa soro lati fi emi imoore han, Tunde Adeyemo dupe pupo lowo ileese City
People bi won se kaa ye gege bi eni ti won fun lami eye ojo naa.
O so pe bawo
lo se maa ri nigba teeyan ko ba jale tabi saya gbangba fun ole lawujo. O ni
pataki nla ni awoodu naa je foun gege bi oniroyin to tun mu ise keji mo lati
maa pa fi awon eeyan lerin, lati so won di onile ti ara won.
Tunde wa fi
awoodu naa sori Olodumare, iyawo e ati gbogbo awon osise Pelican-Valley, awon
onibara e pelu gbogbo akegbe e ti won je oniroyin atawon alabasise po e.
No comments:
Post a Comment