Egbe oselu APC ti kilo fegbe oselu
APM tipinle Ogun lati kowo omo won boso
lori kiki oselu bo iku agba oselu nni to jade laye, Oloye Jide Awosedo.
Ninu atejade kan ti Ogbeni Tunde
Oladunjoye, fidihe akowe olupolongo fegbe oselu APC tipinle Ogun fi sita losan
yii ni won ti fi ilodi won lori atejade ti Oloye Derin Adebiyi, alaga egbe
oselu naa tele fi sita fun ti ibanikedun Oloogbe naa.
Lakoko, won ni atejade naa ki i se
ojulowo latinu egbe naa, nitori ko si oloye egbe kankan to fowo sii, ati pe
gbogbo awon eeyan gan-an ti mo pe ise awon alatako egbe naa ni.
Oladunjoye tun fi kun oro e pe awon
alatako oselu ti won wa da ipolongo Aare Buhari, ti won tun le oko mo on nigba
to wa si papa MKO Abiola lojo kokanla, osu keji, odun yii.
O tun salaye pe edun okan lo je fawon
fun iwa odaju tawon eeyan naa hu ti won fee ki oselu bo iku agba akoni oloselu
naa pelu awon ti won satileyin fun won.
Fun igbese ti won sare gbe naa
lakooko tiku naa bawon ebi naa lojiji, ti won ko tii bo ninu re lawon eeyan naa
wa fee so di oselu, won ni eyi ko dara to.
O wa sapejuwe Oloye Jide Awosedo, gege bi eni owo tooto, to
gbe igbe aye onirele, o lawon ko mo nnkan tawon eeyan naa fee ri gba nipa kiki
oselu bo iku e.
Won nireti pe atejade ti won gbe
jade ki i se pe won fi n gbero lati le oko mo awon eeyan pataki ti won ba wa
sibi ayeye isinku lakooko ti won ba fi si.
O wa pari oro e lati ke si awon
agbofinro pe ki won ma sasun para, o wa ro awon omo egbe oselu naa lati wa ni
alaafia pelu akoko ibanikedun yii, pelu idaniloju pe awon yoo kan si ebi agba
oselu naa nipa ayeye isinku e.
No comments:
Post a Comment