Adesina Okegbenro ti inagije e n je
Eniba, ti so pe ti won ba ni ki won wo awon ipa toun ti ko ninu egbe awako
NURTW nipinle Ogun ti to lasan lati je koun di alaga egbe naa ati pe ko si
awitunwi asan, oun ni ipo naa to si bayii.
O soro yii lakooko to n ba oniroyin
soro, O ni aimoye ipa loun ti ko lati mu idagbasoke ba egbe naa nipinle Ogun, o
si da oun loju pe akoko toun naa ree lati di alaga.
Ninu oro e lo ti soo di mimo pe lati
ori kondokiti labe dereba to n wa moto loun ti bere ni garaji kuto. Leyin naa
lo tun so pe ni nnkan bi odun metalelogbon loun fi sise ni garaji Ita- Oshin
nigba ti oloogun Captain Sam Ewang fi wa lori aleefa.
Adesina loun naa ti figba kan je
alaga fidihe ri, ko to di pe won tu egbe naa ka nigba naa, leyin naa lo tun di
alaga ni garaji Kuto fodun meji, ko to di pe ayipada de ba ijoba.
O wa fikun oro e ri pe igba kan tie
wa ti won le oun ninu egbe naa nitori ooto toun se, igba marun un otooto lo ni
egbe lapapo lati Abuja da si oro naa laarin odun 2011 si 2019 pe ki won gba oun
pada sugbon tawon yen lo owo agbara ti won ko tele ase naa.
Eniba tun so salaye pe bi won se da
oun duro nigba naa ki i se Abeokuta nikan lo ti mu ifaseyin ba oun nigba naa,
gbogbo ipinle Ogun ni sugbon iyen ko si oun lokan nipa igbagbo toun ni si
Olorun.
O ni iyen nikan ko, opo ihale lati
gba emi oun loun ti ri gba lodo awon to n sakoso nigba naa, idi niyii to ni oun
fi sa fun emi oun toun gba orileede Amerika lo.
O so pe oun mo pe ipo alaga awako
NURTW ki i sere omode, o lo nii se pelu eni to mo nnkan tawon eeyan ba n fee,
to si tun le duro ninu otito.
Okunrin yii la gbo pe o sonigbowo
fawon omoleyin e lati sise fun Gomina Dapo Abiodun lakooko ipolongo to koja, o
ni nigba toun ti foju winna gbogbo isele to sele soun yii loun se so pe oun
nipo alaga egbe awako naa kan.
No comments:
Post a Comment