Adele oga agba fun ileese to n ri si
idokowo ati nnkan ini nipinle Ogun iyen Property and Investment Corporation
(OPIC), Arabinrin Ibiyemi Adesoye, ti mu idaniloju wa pe ileese naa ti setan
lati pese opo ileegbe ti ko koja agbara fawon araalu atawon ileese nla fun
itesiwaju idagbasoke ipinle naa.
Obinrin se idaniloju yii lakooko to
n saaju awon alakoso ileese naa lo sabewo si igbakeji gomina nipinle Ogun,
Noimot Salako-Oyedele ni ofiisi e to wa ni Oke- Mosan, niluu Abeokuta, nibi to ti
so nipa awon ise tileese OPIC naa ti se ati lati fi gba imoran lenu e lori bi
idagbasoke yoo se de ba ileese naa.
Adesoye fikun oro e pe ileese naa ti ile nla kan ni Agbara,
eyi to to egberun mejo eeka, to si ile bii egberun kan ile ti won ti pin fawon
eeyan bee lo ni awon tun ni kan ni Isheri eyi ti won pe ni MTR Gardens, bee lo
tun menuba awon ile nlanla ti won ni lawon agbegbe bii Agbara/ Igbesa ,
Isheri , New Makun City and Orange Valley Estate to wa niluu Abeokuta.
Bakan naa ni adele oga agba naa tun
salaye awon tun ni awon ile olowo nla lawon bii OPIC Plaza, ni Ikeja, niluu
Eko, OPIC Towers, ni Oke-Ilewo, Abeokuta ati ile igbafe iyen OPIC house and
Event Centre, to wa ni Isheri.
Adesoye wa pe fun ajosepo pelu
awon ileese aladani, ati pe eto kan ti won sese sagbekale e to nii se pelu
molebi iyen Family Home Funds ( FHF), je erongba ijoba apapo pelu ipinnu lati
pese awon ile olowo pooku fawon eeyan lorileede yii, eyi ti ipinle Ogun je okan
ninu won.
Nino oro igbakeji gomina, Noimot
Salako- Oyedele, o dupe gidigidi lowo awon alakoso ileese naa ti won wa sabewo
sodo e. O ni erongba ijoba Dapo Abiodun ni lati rii pe ipese ile je irorun
fawon eeyan ipinle naa.
O wa gboriyin fun won lori eto
ikowojo ile molebi iyen Family Home Funds ti won sese bere gege bi igbese to
dara ni eyi to ni yoo mu irorun ba awon araalu nipa oro ileegbe.
No comments:
Post a Comment