Mo dariji gbogbo awon to ba ro pe awon se mi- Dapo Abiodun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 1 June 2019

Mo dariji gbogbo awon to ba ro pe awon se mi- Dapo Abiodun


Gomina Dapo Abiodun ti so pe oun ti dariji gbogbo awon to ba ro lokan won pe awon se oun, nitori pe gbogbo ibi ti won ro pe awon se nigba naa ire lo ja si foun, oun ko si di enikeni sinu ninu gbogbo won.

O soro yii ni mosalasi Jimo, to wa ni Kobiti, niluu Abeokuta, lakooko ti won se akanse irun jimo fun ti pe okunrin naa di gomina.

O so pe bo tile je pe orisirisi ni nnkan to sele seyin loun ti  gbegbe nitori gbogbo e ti dohun itan, nitori e loun se so ni mosalasi pe gbogbo awon to ro pe awon oun, loun ti dariji, nitori oun ko nii lokan pe awon kan se oun.

Dapo Abiodun tun so pe o se e se ko je pe bawon eeyan naa ko ba hu awon iwa ti won hu, oun le ma di gomina, amo ti Olorun so ibi di ire foun.

Bee lo tun so fawon olori elesin musulumi pe ijoba toun ki i se fun molebi oun tabi ti igbakeji oun bi ko se ti gbogbo araalu, oun yoo si ri daju pe gbogbo awon ileri tawon se lakooko ipolongo

Dapo Abiodun tun tan imole idi to fi sise po pelu awon ti won jo gbapoti ipo gomina, o ni awon rii pe ero okan won papo mo ti won lati mu ipinle Ogun goke agba, lawon se mu won mora, lara won ni 

Omooba Gboyega Nasir Isiaka, to wa nibi irun pataki ojo naa.
O tun lo akoko naa lati tun fi so fun won pe gbogbo awon ibi to latunse lawon yoo sise si kaakiri ipinle Ogun, awon ko ni fi apa kan da apa kan si.

Idi niyii to fi nileese OGROMA to ti wa laye igba Gbenga Daniel yoo pada bo si po. Bee lo si gbogbo awon osise ti won ti je lowo ajemonu ni won yoo bere si nii san diedie, titi ti won yoo fi san gbogbo e tan, to fi mo awon osise feyinti.

O wa ro akoko naa lati fi ro awon omo ipinle Ogun lati sise po pelu ijoba tuntun yii, ki aseyori le de ba gbogbo nnkan ti won n fe.

Ko to akoko naa ni Baba Adinni ile Egba, Alaaji Rasheed Raji ti ro Gomina Dapo Abiodun lati fi ti Olorun siwaju ohun gbogbo to ba n se nitori oun lo yan an sipo.

Bee naa ni Alake tile Egba, Oba Adedotun Aremu Gbadebo ti gba gbogbo omo ipinle Ogun nimoran lati fun Gomina naa laaye lati se awon ise fee se nipinle naa.

No comments:

Post a Comment

Pages