Lati osan, ojo Eti, Furaide, ti iroyin ti gba gbogbo igboro ipinle Ogun pe gbogbo awon oba bii marundinlogorin ti won gbade ojiji laarin osu keji si osu karun un taa wa yii lowo gomina tele nipinle Ogun, Ibikunle Amosun ni won ti so pe ki won si si ade ori won, ki won pada sile won, nitori ijoba fee se agbeyewo lori bi won se dori oye, lara awon oba naa ko ti bale mo.
Ariwo gbese
de, gbese de, ni won so pe opo ninu won pa, nigba tawon mii in si n so pe owo
ti wogba, awon to sun mo won to ba wa soro si so pe se lara nnkan won bayii.
Gege bi a se
gbo, nibi ijokoo tawon omo ile igbimo asofin ipinle naa se lojo Furaidee yii ni
won ti penupo gbe abajade pe ki won sagbeywo lori awon oba tipatipa ti won ni
won sare yan an naa lakooko tijoba to pari yii fee kogba sile.
Won ni yiyan
ti won yan awon oba marundinlogorin naa sipo lo ti da wahala sile laarin agbegbe ti won joba le
lori ti ko si ti ni ojutu, nitori e lawon omo ile igbimo naa se fagile yiyan
won.
A o ranti pe
nigba to fee ku ose bii meloo kan tijoba naa fee kogba sile ni Ibikunle Amosun
yan awon oba, bale marundinlogorin, eyi to waye ni gbongan awon oba, ni ofiisi
gomina.
Bakan naa ni
won tun ti pase fawon alaga ijoba ibile ati ti idagbasoke to fi mo awon
kanselo nipinle Ogun lati fipo naa sile
ki won si rii pe won fa gbogbo ise kanse naa le awon olori isakoso ijoba ibile
kookan, bee ni won gbodo wa farahan fawon omo ile igbimo asofin, ko to di ojo
keje osu to n bo.
No comments:
Post a Comment