Odomokunrin
kan omo odun mejilelogun, Abdul Tafawa lo ti ha sowo awon eso alaabo So Safe
Corps lori esun pe oun atawon eeyan e, meji kan ti won si n wa bayii loo
digunjale.
Gege bi a se
gbo, lojo Aiku, Sannde, ojo kerindinlogbon, osu yii ni won so pe Abdul atawon
eeyan e meji loo ja awon to n gbe ni Sparklight Estate, Isheri lona Eko si
Ibadan lole ni nnkan bi aago meji oru.
Awon ebi ti won ja lole ni won so fun fawon
eso alaabo So Safe Corps yii pe se lawon eeyan naa wole awon lojiji pelu ibon
ati ada lowo won, ti won si hale pe awon yoo pawon ti won ba le pariwo.
Won ni leyin ti won ja awon eeyan naa lole
ti won ko won leru owo, foonu, laptops atawon nnkan mii in, ti won sa lo lawon
alaabo naa sa tele won ti won si mu Abdul nigba tawon yooku sa lo.
Gbogbo nnkan ti won ji gbe naa la gbo pe
awon alaabo So Safe Corps gba pada lowo won ti won si fa Abdul towo te naa le
awon olopaa tesan ekun Ojodu Abiodun lowo tawon si ti n te siwaju ninu iwadii
won.
No comments:
Post a Comment