Alaabo So Safe Corps ti mu ore meta to ji okada gbe ni Idi- Iroko. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 1 June 2019

Alaabo So Safe Corps ti mu ore meta to ji okada gbe ni Idi- Iroko.


Lojoruu, Wesidee, ojo kejindinlogbon, osu yii, lowo awon alaabo So Safe Corps te awon meta kan lori esun pe won ji okada gbe, bee ni won tun fee pa a danu.

Awon towo te naa ni Adeyemi Dauda, eni odun mokandinlogbon, to n gbe ni ojule kerinla, Razaq Odedaye,Idiroko, Gafar Tela, omo odun mokanlelogun  to n gbe ni ojule keedogunAseko, Idiroko, ati Segun Durotade eni odun mejidinlogbon.

Ohun taa gbo pe o sele ni pe ni nnkan nii aago mokanla ale lojo kokandinlogbon, osu yii lawon afurasi towo te yii, Gafar ni ki olokada kan toruko e n je Emmanuel Abiala, ni Ojuuroko lona Idi- Iroko gbe awon loo si ilu Ibatefin nijoba ibile Ipokia.

 Bi won se de aarin ona ni won so pe Gafar la irin nla mo olokada naa lori tawon mejeeji si jo subu lule, ti Gafar sare dide to gbe okada naa loo si orileede Benin lati wa eni to maa baa raa,

Sugbon se ni won ni okan lara osise alaabo So Safe Corps se bi eni to fee raa, nibi ti won si ti n duna dura lowo ti te Gafar, ti won si muu pada wa si Ita egbe lorileede yii,

Segun Durotade ni iwadii fi ye wa o se ayederu risiti fun okada ti won ji gbe ti nomba e je bajaj boxer ,    EKY 545 QP.  Awon meteeta towo te naa ni won ti fawon le olopaa IdI- Iroko fun itesiwaju iwadii won.


No comments:

Post a Comment

Pages