Pasito atawon omo ijo e to fun loyun |
Ninu iwe mimo Bibeli lo ti so pe nigba ikeyin ojo orisirisii nnkan ni yoo maa sele, opo awon wolii ni yoo dide, irufe isele yii lo waye nipinle Enugu, nibi ti Pasito kan ti foyun ta ogun ninu awon omo ijo re lore lofee.
Timothy Ngwu ni won pe oruko pasito naa, ojo ori e ko si tii
ju odun metalelaadota lo, bee ni a gbo pe oun ni oludasile soosi kan ti won pe
ni ise iranse ogba ajara, iyen Vineyard Ministry of the Holy Trinity.
Okunrin Pasito naa ni won so pe o ni emi Olorun ba le oun
lati foyun ta awon omo ijo oun lore, labe bo ti wu, ki won po to, ki ise iyanu
le towo won se.
Okan lara omo ijo Pasito naa salaye okunrin to pe ara e ni
ojise Olorun loun fee bowo fun ase ti emi mimo pa foun lati muu se, idi niyii
lo se foyun tore fawon omobinrin ijo e, ti emi yen ba ti so fun, opo awon iyawo
ile naa ni won gboyun ofe yii.
Bee ni iwadii fi ye wa pe obinrin ti Pasito naa ba ti fun un
loyun, to si bimo, omo naa ati iya e ti domo ijo lojiji.
Oro Pasito naa ti de odo awon olopaa bayii, won ni iyawo e
ti ara e ko gba a mo lo loo foro naa to won leti, koda won ni aburo iyawo e
fori ko, oyun emi mimo to fawon omo ijo e yii.
Ninu oro Pasito afoyun tore naa, o so pe oun ki i ba iyawo
oniyawo sun a fi eyi ti oko e ba fee gbohun si emi mimo.
Iyawo marun un pelu omo metala ni won so pe Pasito naa ni
tele, ko to di pe o gba ase lowo emi mimo gege bi won lo se wi pe koun maa
foyun tore.
Ni bayii, agbenuso awon olopaa ni Enugu, Ebere Amaraizu, ti
jeri si isele naa, o ni pasito naa ti foju bale ejo.
No comments:
Post a Comment