Igbakeji gomina ipinle Ogun gba awon odo nimoran lori igbeyawo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday, 2 June 2019

Igbakeji gomina ipinle Ogun gba awon odo nimoran lori igbeyawo


 
Arabinrin Noimot Salako-Oyedele , to je igbakeji gomina nipinle Ogun, ti gba awon odo nimoran lati rii pe won se suuru, ki won si foju bale daadaa, ko to di pe won mu eni ti okan won fee gege bi ololufe won.

Obinrin yii soro naa lakooko to wa nibi ayeye igbeyawo Omooba Adedamola Bodunrin Tejuoso, to je omo Oba Osile tile Oke- Ona Egba, Oba, Dokita Adedapo Tejuoso ati  iyawo e, Oluwadamilola  Elizabeth , eyi to waye ni soosi, Chapel of  Christ the Light , Alausa, Ikeja, niluu Eko, lojo Abameta, Satide to koja yii.

Ninu oro e lo ti sapejuwe igbeyawo gege bi nnkan pataki ninu igbe aye eda laarin okunrin ati obinrin sugbon o ni ko wa ye ki won wa kanju ju Olorun lo, nitori eni to ba sare wonu igbeyawo, yoo sare pada ni.

Igbakeji gomina naa tun so pe oun to tun se pataki lati fi igbeyawo naa le Olorun lowo, nitori oun nikan loba atoni, to maa n to eda sona nipa irinajo yii.

O wa lo akoko naa lati ki molebi awon naa ku oriire, fun pe Olorun je ki won ri iru ojo ayo bii toni in, o wa gbadura pe ki Olorun se igbeyawo naa leyii to n ba ni kale.

Ko to to akoko yii, ni Bisobu  ijo African, ekun ti Egba, Eni-Owo Peter Oyero, ninu iwaasu e ti mu awon eeyan loo sinu iwe Efesu ori karun un ese kokanlelogun, nibi to ti gba toko-tiyawo nimoran lati bowo fun ara won, ki oko mo ojuse e ninu ile,ki iyawo naa si mo ojuse e, ki ibasepo to lagbara le wa ninu igbeyawo naa.

Lara awon eeyan pataki to wa nibi igbeyawo naa ni Oga- Oloogun Oladipupo Diya, Mosunmola Dipeolu,to je adajo agba nipinle Ogun, Bola Obasanjo, iyawo Oloye Olusegun Obasanjo, Senetor Lanre Tejuoso, atawon eeyan pataki.

No comments:

Post a Comment

Pages