O soro yii lakooko to n fesi si
iwaasu Bisobu ekun ile Egba tijo Anglican Communion, Eni- Owo Emmanuel Adekunle
se nibi
akanse isin idupe to waye ni ijo Cathedral,
St. Peters, Ake, niluu Abeokuta.
Bee lo tun mu dawon loju pe ijoba
oun yoo pese imayederun fawon to wa ni igberiko nipa titun ona se,idasile awon
ileeese
ati pe nipa oro eto eko, o lawon ti
n gbe igbese lati pese idokowo awon ileese aladani bi yoo se po nipinle yii.
Dapo Abiodun tun so pelu idaniloju
pe awon ti n gbero bi apero yoo se waye nipa eto eko nibi ti won yoo ti soro
lori bi ipinle yii yoo se pada sipo asiwaju ti won wa tele nidii eko.
Ki Gomina Dapo Abiodun, to soro ni
oniwaasu ojo naa Eni- owo Emmanuel Adekunle ti kilo fun gomina naa ko ma se da
awon agba nidii oselu ti won sise fun un lakooko ipolongo ibo nu.
Ojise Olorun naa tun so pe ohun to
se pataki fun gomina naa ni lati fi ti Olorun siwaju gbogbo nnkan to baa se
pelu iberu Olorun.
O ni Okunrin naa ni oore ofe lati
maa gbamoran lowo awon agba oselu yii nipa isakoso e, ki i se pe ko wa dawon nu
bi omi isanwo.
Eni- owo Adekunle so pe oun ko nii
pe won ni baba isale nitori awon ti won n pe ni baba isale ni won maa n ri
oselu bi okoowo, lati le lo agbara nigba ti nnkan ba n dun.
Bisobu naa wa gba Dapo Abiodun
nimoran lati lo ipo e lati fi satunse lori eto eko to ti fee mu itiju ba ipinle
Ogun lawon yara ikawe.
O ni ki Gomina ranti pe abe awon
oluko lo ti jade nitori idi eyi ko se itoju awon oluko daadaa, ko ma se fowo je
won niya paapaa awon oluko feyinti, ko rii pe o mu inu won dun.
Lara awon to wa nibi isin idupe ti
won fi ka ese eto olojo mewaa ti won se fun ti ijoba tuntun yii ni Aare Olusegun
Obasanjo, Otunba Gbenga Daniel, Donald
Duke atawon oba alaye pelu awon eeyan jakanjakan niluu.
No comments:
Post a Comment