Abiodun Oyefusi |
Omooba-binrin Abiodun Oyefusi,
oludije seneto labe egbe oselu PDP nipinle Eko ninu ibo to koja yii, ti
gboriyin fun Aare orileede yii, Mohammed Buhari lori bo se fowo si ojo kefa osu
kejila gege bi ayajo ijoba tiwa-n-tiwa, eyi ti won ti bere lodun yii gege bi
igbese to dara,
Ninu atejade ti obinrin naa fi sita
lo ti salaye pe bi won se fayajo ojo bu ola fun Oloye MKO Abiola, eni to jawe
olubori ninu ibo odun tun je ipinle rere lati fese ijoba awarawa yii le le lona
tooto.
Oyefusi to
tun je okan lara omooba-binrin Oloogbe Oba Salaudeen Oyefusi,Ayangburen tiluu
Ikorodu tun wa gba Aare Mohammed Buhari nimoran lati teter gbe igbese lori
ijoba tiwa-n-tiwa nipa fi fawon asofin
loore ofe lati tete maa gba abadofin won wole.
O ni bo ba n se tete fowo si awon
abadofin bee yoo tete maa ran ise ofin lowo paapaa nipa lati gbogun tawon iwa
ibaje lawujo. Bee lo tun ro o lati sise lori abajade esi ipade apapo ti won se
lodun 2014 iyen laye igba ti Goodluck Jonathan fi je aare, ko si gbaa wole fun
idagbasoke orileede yii.
Akinkanju obinrin ninu egbe oselu
PDP tun salaye pe gbigba abo ipade naa wole yoo tun ran opo ipenija ti orileede
wa n koju lakooko yii wole.
O wa lo akoko naa lati ki awon
asofin tuntun eleekesan ku oriire fun ti ayeye ifilole ti won se fun won pelu
amoran pe ki won rii pe won ja takuntakun lati gbogun ti iwa ibaje ninu isejoba
tuntun taa wa yii.
Oyefusi ni oun tun ro awon asofin
naa lati sise won gege bi ofin ti laa kale fun won kawon araalu le jafaani
ninu, ki won si sora fun imotara eni nikan.
|
No comments:
Post a Comment