Onimo-ero Noimot Salako- Oyedele, igbakeji gomina
nipinle Ogun ti mu da awon eeyan ipinle naa loju pea won yoo tete bere ise
atunse lori awon ona to ti baje, eyi to n ko isoro bawon araalu paapaa julo
lakooko ojo yii.
O soro yii lakooko to n sabewo sawon
agbegbe kan ni Ijebu, iyen Ogun East, o ni opo awon ibi ti isoro wa lawon ti mo
tawon si ti mo okunfa e, o ni ijoba yoo wa opin si isoro sawon ipenija naa
laipe.
Salako Oyedele tun so pe
" A ti loo kaakiri lati mo ona taa le gba lati wa ojutu sawon
ipenija to n koju awon eeyan wa nipa ona oju titi. Bee la tun lo anfaani naa
lati mo pato awon ibi ti ise ti le tete bere, taa si bere laipe yii. ".
O tun so pe lara erogba
ijoba lati fopin si sunkere fakere to maa n waye lawon ona kan nipase ona ti ko
dara, o lawon ise ti bere lawon ona bii Oru ati Ilaporu, lona Ijebu-Ode.
O
ni awon tun ti gbo iroyin pe ni gbogbo
ijoba ibile ni won ti so fun lati so won oju ona to se pataki fawon araalu,
pelu idaniloju pe ise yoo bere ni kiakia.
Lara awon to tele igbakeji gomina
sabewo naa ni akowe agba nileese to n ri si oro ise ati imayederun, Onimo-ero Kayode
Ademolake atawon osise ijoba mii in.
Awon ibi ti won sabewo loo ni Ijebu
Mushin- Owu-Ikija 4.5 KM Ogbogbo- Igbeba, Balogun Kuku/Oke Aje-Alapo 1.4 KM ati
Ejirin- Imowo/Oluwalogbon .
No comments:
Post a Comment