Ogbeni Samson Oyeledun, to je agba
oje ninu ere idaraya lorileede yii ti fatileyin e han lori bijoba tuntun
nipinle Ogun, se fee gbe igbese lati dawole idasile ere idarata gege bi ona to
dara to si tun le mu idagbasoke ati igbega baa.
Okunrin naa soro yii lakooko to n
bawon oniroyin soro ni papa isere MKO to wa ni Kuto, niluu Abeokuta. O so pe idasile
to je pe eni to mo nipa ere idaraya ni yoo sakoso e je eyi ti won ti n gbero e
tipe, ko to dip e o fee wa si imuse bayii.
Oyeledun tun so pe igbese naa yoo
tun je ki oro aje tun gun rege, ti yoo sit un fawon olubanidowopo nidii ere idaraya
ni ore-ofe lati dawo lee lori, tawon onigbowo naa yoo tun wa lati mu idagbasoke
ba ere idaraya.
Okunrin to ti figba marun un otooto
gba ife eye nibi ere idaraya ere sisa, to si tun se daadaa lawon ere sisa lawon
orileede bii Brisbane, Australia atawon
orileede mii in tun so pe bi ijoba Dapo Abiodun se gba lati gbe igbese yii
fihan pe idagbasoke yoo tubo ba awon ere naa, ti yoo si mu kawon odo ko fife
han si.
O ni o je okan lara ibi ti ijoba Seneto
Ibikunle Amosun, to je gomina tele nipinle naa ti mu ikuna ba idagbasoke ere
idaraya, to si je edun okan gidi.
O tun ni bi iru igbese bee waye yoo
ran atunto ere idaraya lowo, pelu afikun pe iru nnkan bee ti won ti n se ni Eko,
Abia, Ekiti, Ondo, Delta atawon ipinle mii in ti je kawon olokowo adani fi ife
han si ere idaraya.
O wa gba Gomina nimoran lati ma se
je ko fale rara, ki won tete bere igbese naa.
No comments:
Post a Comment