Ojise Olorun Stephen Olamilekan Abiodun, ti soosi All Saints Anglican
Church, to wa niluu Ilaro, ti gba Gomina tuntun ti won sese dibo yan Dapo
Abiodun nimoran lati yera fawon nnkan to ti gbe awon asaaju e, ti won ti di gomina nipinle
Ogun subu to ba fee se aseyori ninu ijoba e.
Lojo Aiku, Sannde, ni Ojise
Olorun gba gomina tuntun naa lamoran yii lakooko to n soro nibi isin akanse fun
ti imurasile igbejoba tuntun kale, eyi to waye nile ijosin naa,
O ni ko ma je ki
enikeni ko sibasibo boo ninu awon nnkan to ba fee se, ko si rii pe o se suuru
ati iwadii daadaa ko to di pe o dawo le awon nnkan wonyii.
O ni ko ma je ki iru
awon nnkan to sele pelu ijoba to n kogba sile yii sele si, nipa si sare se awon
ise akanse to ye ki won fi suuru se,ti ko fee mu itumo gidi kan da ni.
O tun so pe bi gomina
tuntun ba fee se aseyori ninu isakoso e, o gbodo kekoo lara awon asise ti Olusegun
Osoba, Gbenga Daniel atawon mii in ti won saaju ti se, ko si yera patapata.
Ojise Olorun Stephen
Olalekan tun so pe Amosun ko le pari awon ise akanse laaaro sibe o lo tun bere si
nii sare ni ale, to tun wa bere si nii baa won nnkan je ni wakati kokanla ojo
bi igba ti saa e ko ni pare mo.
Ninu iwaasu Eni- owo Michael
Oluwarohunbi, to je olori bisoobu ni ekun Yewa eyi ti akole e je gbogbo ipo lo ni nnkan to ro
mo on o gba Dapo Abiodun nimoran lati maa ranti pe won yan an lati sin awon
eeyan.
Bee lo gba gomina naa
nimoran lati ma se se eleyemeya nipa awon ise akanse, ko ranti awon eeyan Ogun
West nipa nnkan to ba fee se, ko yo won kuro ninu omo orukan.
Nigba toun naa soro
nibi isin naa, Dapo Abiodun seleri pe ko ni si ojusaaju ninu isakoso oun ati pe
aye yoo wa fawon eeyan lati maa bijoba yoo se maa lo.
Bee lo ni ijoba oun
yoo tun kojumo awon ise atunse lawon igberiko pelu idaniloju pe ileese to n tun
ona se tipinle Ogun iyen Ogun State Road Maintenance Agency (OGROMA) yoo pada
bo sipo.
Abiodun tun seleri pe laarin ogorun-un ojo isejoba oun,
ijoba oun yoo le so pelu igboya pea won pese ilera to peye, ileewe tijoba lawon
woodu to wa nipinle Ogun.
Lara awon to josin
pelu Abiodun ni Seneto Solomon Olamilekan Adeola, Seneto ti won sese yan ni
Ogun West; Tolu Odebiyi, Suraj Adekunbi,olori ile igbimo asofin ati igbakeji e,
Kunle Oluomo, Tunde Oladunjoye to je akowe olupolngo fegbe oselu APC
nipinle Ogun.
No comments:
Post a Comment