Otunba Gbenga Daniel,
gomina tele nipinle Ogun ti so pe oro Seneto Ibikunle Amosun, gomina to fee
kogba sile bayii, ko jo oun loju, nitori gbogbo aye lo ti mo on gege bi oba
oniro, ti ko si ooto kan lenu e.
Ninu atejade kan ti
Ogbeni Steeve Oniyide gbe jade loruko Gomina naa lati fi tako oro ti won ni
Amosun so pe ijakule loun jogun nipinle Ogun lodun 2011 lakooko toun gbakoso.
Won ni oro yii lo jade
lenu akowe ijoba nipinle Ogun, Taiwo Adeoluwa loruko Amosun nibi ayeye kan.gbogbo
oro ti won lo jade lenu okunrin naa loruko oga e lo kun fun iro pe oun ba ijakule
nitori ko si aabo to peye.
O ni fun bi odun mejo
ti okunrin naa ti n se ijoba lawon eeyan ipinle Ogun ti mo pe won bi iro mo
gomina naa ni, nitori won ti mo pe ko si oro kan to jade lenu e, ti ko fi iro
kun.
Daniel so pe eni ti
won ba ti mo iwa e, ko ye ki won maa fun ni esi gbogbo oro to ba so, sugbon
awon fee fun lesi eleyii nitori oro to so gbeyin yin, ti jade lawon ori ero
ayelujara, nitori ojo iwaju ati oruko toun ti ni.
O so pe o se ni laanu
pe eni to ti se ijoba fodun mejo, ti jewo ara e nipa bi opolo e se ri nipa eko
nigba to sOapejuwen ipinle Ogun fodun 2011 gege bi eyi to ja nikule. Abuku lo
so pe lo je fawon omo bibi ipinle naa to fi mo awon osise ti won sa agbara won
lati fi sin ipinle won.
Daniel so pe ko le ya
oun lenu idi tawon araalu fi n ka iye ojo to ku ti Amosun yoo gbejoba sile, eyi
ti ko ju ojo marun un lo mo.Nitori inu won n dun pe awon yoo bo lowo ijoba
oniro.
O so pe o wa ninu itan
pe owo to wole fawon idokowo laarin odun 2003 si odun 2011 ko fee siru e, eyi
to tun mu ki oro aje gun rege nipinle naa tawon omo bibi ipinle naa si n ri ti
won se fun idagbasoke.
O menuba awon ise ti
won se to mu owo wole daadaa ti akosile e si wa bee lo tun so nipa bi won se pa
awon eeyan kan lakooko Amosun ti won ko si ri an
abajade iwadii naa di
akoko yii.
Awon eeyan bii Alaaja
Elewuju, Iyaloja oja Ijebu-Ode Ogbeni Wale Adufe, to je oluko nileewe TASUED,
Omooba Yomi Bamgbose (osiseVIO], an alaga egbe oselu CAN ni ijoba ibile Ogun
Waterside, Oloye Tola Okuneye ti won pa ni inu soosi ni Ijebu Igbo.Opo ija awon
omo egbe okunkun kaakiri Sagamu. Ati beebee lo.
O ni sebi oju Amosun
ni won ti so aare orileede yii lokuta eemerin ototo ni won lepa emi gomina
tuntun ti won sese dibo yan Dapo Abiodun lakooko ipolongo.
Bee lo ni awon omo
ipinle Ogun ko ma gbagbe nnkan to se lakooko isakoso e fun Onarebu Remmy Hassan
ati Onarebu Adija Oladapo Adeleye nigba tawon yen si je omo ile igbimo asofin
ti won lo ba ile won je.
O ni Onarebu Maruf
Musa to wa lati Waterside naa ko le gbagbe ile itaja e nla ti won wo danu ati
bi won se ba ohun ini Onarebu Femi Ilori je ni Adatan.
Laipe yii naa ni won
tun ba ofiisi Onarebu Oluomo to je igbekeji olori omo ile igbimo asofin je, o
se je pe gbogbo awon ti ko ba se tie ni won se nijanba, O ni se abo to peye wa
ni gblogbo iru nnkan bee sele ninu ijoba
e/
O wa pari oro e pe o ya oun lenu pe Amosun ti
sowo abo lori nnkan toun atawon ebi e n janfaani.
No comments:
Post a Comment